OTUNBA MIKE ADENUGA: O̩mo̩nìyàn ń pàté̩wó̩ bí e̩lé̩yinjú àánú s̩e di e̩ni o̩dún mó̩kànlélàádó̩rin, 71

OTUNBA MIKE ADENUGA: O̩mo̩nìyàn ń pàté̩wó̩ bí e̩lé̩yinjú àánú s̩e di e̩ni o̩dún mó̩kànlélàádó̩rin, 71

– Olùdásílè̩ Globacom s̩e àso̩dúnmó̩dún

– Bí Adenuga s̩e ń soore tó lowó re̩ ń búré̩ké̩ síi

Orin idunnu ni o̩po̩lo̩po̩ eniyan n ba ogunna gbongbo onise̩ okowo, iye̩n Dokita Mike Adenuga, ko̩ bayii o, nitori o ti di e̩ni o̩dun mo̩kanlelaado̩rin – 71.

O̩jo̩ ko̩kandinlo̩gbo̩n osu ke̩rin o̩dun yii ni o̩dun tun pe, ti odun ko, ti Adenuga si tun se ojo ibi miran loke eepe.

Gege bi ise re, ko jo pe Adenuga fe pe elere tabi ko da agbo apeje nla sile.

Eni ti opo eniyan ti mo bi eni mowo ni. Werewere lo maa n saye, kii pariwo, kii sii maa n ti ode kan bo si omiran.

Ni ti Adenuga, ibi gereye laa ba agba ni. Kii se eni to maa n sannani kaakiri.

Dipo bee, awon ohun ribiribi to maa n se ni awon eniyan maa n ri.

A maa n gbo oruko re ni rere lati ara awon ile ise nla nla re, bii Globacom ati Conoil.

Ibi awon ile-ise yii ni o ti n fun opo eniyan ni anfaani lati sise oojo won, ti won si n lo sile pelu owo ribiribi.

Adenuga tun ni ipin pupo ninu awon ile ise miran, to fi mo Julius Berger to maa n se ona nla nla.

Ko tan sibe o: opo awon oludokowo keekeeke ni won ni ajosepo pelu awon ile ise Adenuga, ti awon naa n gba ise lorisiirisii, ti owo si n bo si awon naa lapo.

Eni ba lo si olu ile ise Globacom ni Eko ni yoo mo ohun ti a n wi.

Sugbon kii se awon to n ba Globacom tabi Conoil dase po nikan lo n je anfaani owo Adenuga.

Ohun ti o se pataki ni pe aramanda olowo tabua naa je eni kan to maa n se oore pupo.

Ki a ma fi oro s’abe ahon so, Adenuga lawo – eyi to tumo si pe kii se ahun.

Nigba ti Yoruba ba ni ijo Aguda ko je labe Geesi, tabi ti won ni eni to ba Raji je ni yoo pe ni Alakanse, ti won si ni eni to ba Idowu jeun ni yoo pe ni Animasahun, iru olowo Adenuga ko ni won n ba wi.

Opo eniyan lo n je labe re. Opo eniyan lo n je lati apo re, koda Yoruba nikan ko. Ati Awusa, ati Ibo, ati awon eya miiran ni.

IROYIN OWURO gbo pe loorekoore ni Adenuga maa n nawo si opo eniyan ati awon egbe lobaloba, nijoye nijoye, elesin, egbe awon onsowo ati bee bee lo.

Bi awon kankan ko ba tile le jerii si bi Adenuga se n d’erin peeke won, awon alariya Naijeria kan ko le bo ore Olorun mora.

Irufe awon eniyan bee ni won wa ni ate Glo Ambassadors. Awon alariya yii, gege bii awon onifiimu, akorin gbajugbaja ati aderinposonu comedian, ni Globacom maa n gbe milionu yanturu fun, ti won fi n sise, ti won fi n kole, ti won fi n ra moto, ti won si tun fi n se ohun ribiribi miran.

Lara awon osere ti won ti won ti won ti je Glo Ambassadors ni Wizkid, D’Banj, PSquare, Flavour, MI, Wande Coal, Omawumi, Burna Boy, Ego ati Sani Danja. Bakan naa awon Asake, Kizz Daniel pelu Chike naa ti jeun soke pelu Glo Ambassadors.

Idi niyi ti iru awon alariya naa kii fii ko iyan Adenuga kere. Won maa n korin rere ki awon ile ise re ni, bo tile je pe Baba Olowo naa kii se eni kan to maa n fe ki eniyan ki oun ni akiikitan. Sibesibe, ko si eni ti kii fi owo ran lowo.

A ko le sai fi kun un pe ile ise Globacom naa kii fi iranlowo ilu, iyen Corporate Social Responsibility, sere. Leyin pe o maa n fun awon eniyan ni ile, moto ati awon ebun nla nla miran nigba ti won ba n se tete oriire, Globacom maa n diidi se akanse oore fun elegbejegbe. Bakan naa, ile ise naa n gbe asa ga, nipa gbigbe owo iranlowo fun awon to n se odun ibile.

Lara awon odun akanse naa ni Ojude Oba Festival ati Ofala Festival ni Onitsha.

Bi Adenuga se wa n se fun onile se fun alejo yii, oke, oke lowo afunni gbe ni oro re.

Dukia re ko din ku. O tun n peleke sii ni.

Koda, ni nnkan bii osu meloo kan seyin ni ajo Forbes, to maa n se atejade awon to lowo julo ni agbaye ati ni orile ede kookan, gbe e jade pe Owo Adenuga tun ti bureke pada.

Won ni oun ni eni to lowo julo sikeji ni ile Naijiria, leyin Alhaji Aliko Dangote.

Hmm, ee wa raye lode bi. Nje bi Adenuga se tubo n goke agba yii ni ti ojo ori, to si n se orile ede ati omoniyan loore, adura ti terutomo yoo maa gba ni pe abudi ni ti omi okun, abudi naa si ni ti osa. Eni kan kii riddii omonigedegede. Omo araye ko ni riddi Adenuga o.

Bakan naa, peregun kii ku boro: Otunba Mike Adenuga, eni to je Opomulero Yoruba, Opomulero Naijiria, ati Opomulero Afrika, ko ni ku boro o.

Oba Oke a je ki eni ti apele re n je THE BULL o tun se opolopo odun loke eepe. Ninu ola nla, pelu ilera to peye.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here