Bí kẹ̀ẹ́kẹ́ márúwá jíjí ṣe jẹ́ àwọn eléyìn lọ́wọ́ tó, ó pàpà yíwọ́
Ọ̀rẹ Òtítọ́jù
Ọ̀jọ́ gbogbo bí ọdún ni tolè,ọjọ́ kan ṣoṣo ni ti olóhun tí àwọn yorùbá máa n sọ ti ṣẹ báyìí ó,bí ọwọ́ àwọn agbófinró ìpínlẹ̀ Èkó, lábẹ́ ìdarí Kọmíṣánnà ọlọ́pàá, CP Fayọade, ti tẹ géndé mẹ́rin kan tó jẹ́ jíjí kẹ̀ẹ̀kẹ̀ Márúwá ni iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò. Kẹ̀ẹ̀kẹ̀ mẹ́ta ni wọ́n lọ̀ọ́ jí gbé níléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti n ta àwọn kẹ̀ẹ̀kẹ̀ ọ̀hún, kọ́wọ́ tó bàwọ́n.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, to fi ọrọ yii lede loju opo ayelujara rẹ lọjọ Abamẹta, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ileeṣẹ kan ti wọn ti n to kẹẹkẹ Maruwa pọ, ti wọn si ti n ta a, eyi to fikalẹ si agbegbe Ọjọta, nipinlẹ Eko, lawọn afurasi ọdaran yii wọ, ti wọn si ji kẹẹkẹ mẹta gbe.
Hundeyin ni Akọwe ileeṣẹ onimaruwa ọhun lo mu ẹsun wa sileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti Ogudu, ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, pe awọn firi-nidii-ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe ẹda kan ti palẹ kẹẹkẹ mẹta mọ nileeṣẹ awọn ni nnkan bii aago meje idaji ọjọ naa.
Loju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti fọn sode, ti wọn si bẹrẹ si i tọpasẹ kẹẹkẹ naa kiri. Nibi ti wọn ti n fimu finlẹ ni wọn ti ri awọn afurasi ọdaran ti wọn ko fẹẹ darukọ wọn lasiko yii mu.
Hundeyin ni, “Ilu Ondo, nipinlẹ Ondo, ni wọn ti mu afurasi ọdaran kin-in-ni, wọn tọpasẹ rẹ dọhun-un ni, wọn si ba kẹẹkẹ Maruwa tuntun ti wọn ji lọwọ rẹ, nigba tọwọ ba afurasi keji ni agbegbe Mile 12, l’Ekoo, pẹlu kẹẹkẹ kan. Ipinlẹ Ogun, niluu Idiroko, leti ẹnubode Naijiria ati ilẹ Olominira Benin, lọwọ ti ba ẹni kẹta ati ẹkẹrin wọn pẹlu kẹẹkẹ tuntun ti wọn ji ọhun.
O ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn, ati pe kete lẹyin iwadii, gbogbo wọn yoo lọọ kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.