Àwọn èèyàn kan lo ayédèrú ìbuwọ́lù Buhari gbowó tùùlù ní CBN

Àwọn èèyàn kan lo ayédèrú ìbuwọ́lù Buhari gbowó tùùlù ní CBN

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀kánjúà ń dàgbà,ọgbọ́n inú rẹ̀ ń rewájú.
Ìjọba Nàìjíríà ti ta ọlọ́pàá Interpol lólobó láti bá àwọn nawọ́ gán àwọn afurasí mẹ́ta kan tí wọ́n ṣe àdàmọ̀dì òǹtẹ̀ ààrẹ àná ní Náíjíríà, Muhammadu Buhari láti fi gba owó tùùlù jáde ní akoto owó ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, CBN.

Ìwé àkọránṣẹ́ kan tí ìjọba kọ sí Interpol ni wọ́n ti ní àwọn afurasí náà tún ṣe àdàmọ̀dì òǹtẹ̀ akọ̀wé ìjọba sí Ààrẹ Buhari nígbà náà, Boss Mustapha láti gba owó $6.23m ní CBN.

Àwọn afurasí náà gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà ọ̀hún ṣe tò ó ni Odoh Ocheme, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ CBN, Adamu Abubakar àti Imam Abubakar.

Olùwádìí pàtàkì kan tí Ààrẹ Bola Tinubu gbà láti ṣèwádìí àwọn ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ́ CBN, Godwin Emefiele ló kọ lẹ́tà náà sí Interpol gba ọ́fíìsì ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà.
Wọ́n ní ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Odoh Ocheme, ẹni tó ti na pápá bora báyìí àti àwọn méjì yòókù náà gbìmọ̀ pọ̀ láti jí owó tó tó bílíọ̀nù mẹ́sàn-án náírà látara ṣiṣẹ́ ayédèrú ìwé kan èyí tí wọ́n ní Buhari ló buwọ́lu ìwé náà.

Lẹ́tà náà ṣàfihàn pé ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti ṣetán láti ka ẹ̀sùn mẹ́fà sáwọn ènìyàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lọ́rùn nílé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Abuja àmọ́ tí àwọn ènìyàn náà ti na pápá bora.

Ẹ̀wẹ̀, Adájọ́ Inyang Ekwo ti ilé ẹjọ́ gíga Abuja ti gbé àṣẹ kalẹ̀ lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kìíní ọdún 2024 pé kí wọ́n fi òfin gbé àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà.

Godwin Emefiele ló ti ń kojú ìgbẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Maitama fẹ́sùn ṣíṣe owó ìlú báṣubàṣu èyí tí ìjọba àpapọ̀ fi kàn-án.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here