Ẹ se sùúrù fún Tinubu, ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti kú kó tó gbàjọba lọ́wọ́ Buhari – Fayose.

Ẹ se sùúrù fún Tinubu, ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti kú kó tó gbàjọba lọ́wọ́ Buhari – Fayose.

Gbọ́làhàn Quseem

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì tẹ́lẹ̀, Ayodele Fayose, ti sọ pé ó yẹ kí àwọn aráàlú gbóríyìn fún Ààrẹ Bola Tinubu fún àwọn akitiyan rẹ̀ láti sọ ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà jí padà.

Fayose lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels, nibi to ti ni ọrọ aje Naijiria ti di oku ki Tinubu to gba ijọba.

O ni “Oku ni ọrọ aje Naijiria ki ijọba to bọ sọwọ Tinubu, nitori naa, ohunkohun ti a ba n sọ, o yẹ ka kan sara si i.”

Ti ẹ ko ba gbagbe, lẹyin ti Aarẹ Tinubu fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro ni gbogbo nnkan bẹrẹ si n gbowo lori ni Naijiria, ti awọn araalu si n kigbe ebi.

Eyi lo mu ki ọpọ araalu maa sọ pe ijọba Tinubu ko san awọn nitori ebi ti wa niluu, ti awọn mii si n sọ pe mariwo ni ijọba Buhari to kọja, lai mọ pe egungun gan ni ijọba Tinubu yoo jẹ.

Amọ ṣa, Fayose ti sọ pe Tinubu n gbiyanju, o si n ṣe awọn ohun to yẹ lati ṣatunṣe si awọn nnkan ti ijọba Buhari ti bajẹ ni Naijiria.

Gomina Ekiti tẹlẹ naa sọ pe ko si iṣẹ iyanu kankan ti Tinubu le ṣe lati tun ohun ti ijọba ana ti bajẹ ṣe laarin oṣu mẹsan an pere.

Ninu ifọrọwerọ naa ni Fayose ti naka abuku si ijọba Muhammadu Buhari.

O ni o jẹ ohun ibanujẹ pe ijọba Buhari ti fa ọwọ aago ilọsiwaju Naijiria sẹyin gidi, iya rẹ si lawọn araalu n jẹ loni yii.

Fayose ni “Ẹ wo ọdun mẹjọ ti Aarẹ Buhari lo lori oye, ti Tinubu ba tilẹ ni afojusun rere fun Naijiria, bawo ni yoo ṣe ṣe? Ẹ wo gbogbo gbese to jẹ silẹ, bawo ni yoo ṣe yanju rẹ?”

Gomina tẹlẹri ọhun wa rọ Aarẹ Tinubu ko dẹkun ati maa gboriyin fun Buhari nitori Buhari kii ṣe ibukun fun Naijiria.

Lẹyin naa lo rọ Tinubu ko gbagbe nipa Buhari, ko si ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe o mu ileri to ṣe fun awọn ọmọ Naijiria lasiko ipolongo ibo rẹ ṣẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here