Àwọn wo ni ó jẹ ànfààní Ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ pín fáwọn aráàlú?

Àwọn wo ni ó jẹ ànfààní Ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ pín fáwọn aráàlú?

Gbọ́láhàn Quseem

Ijọba orileede Naijiria ti gbe awọn amuyẹ ti araalu gbọdọ ni, ko to di pe wọn le jẹ anfaani owo iranwọ ẹgbẹrun marundinlọgbọn (N25,000) naira ti wọn fẹẹ gbe sita.

Owo naa ni ijọba sọ pe idile mẹẹdogun ni yoo jẹ anfaani yii, ati pe wọn gbọdọ ni awọn amuyẹ to ba ilana ti wọn ka silẹ mu, bi igbe aye irọrun ṣe n le koko.

Bi awọn araalu ṣe n pariwo pe ilu ko fararọ, Aarẹ Bọla Tinubu ti sọ pe niṣe ni wọn yoo bẹrẹ sii fi awọn owo naa ranṣẹ sinu apo ile ifowopamọ awọn alaini ati awọn to ku diẹ kato fun.

Ko to di pe wọn da awọn eto owo iranwọ to wa nita tẹlẹ duro, ọmọ Naijiria ti ko din ni miliọnu mẹta ni wọn ti n jẹ anfaani naa.

Ṣugbọn nitori awọn nnkan ti ko fararọ niluu, ijọba ni lati kede idaduro awọn eto iranwọ naa, sibẹ ijọba ni awọn fẹẹ le alekun awọn to n jẹ anfaani yii si idile miliọnu mẹẹdogun.

Minisita fọrọ eto iṣuna ati alakoso minisita fọrọ eto ọrọ aje, Wale Ẹdun ninu ifọrọwerọ to ṣe laipẹ yii pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels jẹ ko di mimọ pe araalu to ba fẹẹ jẹ anfaani gbọdọ ni nọmba idanimọ apapọ ti a mọ si National Identification Number (NIN).

Lara awọn amuyẹ miran to tun mẹnuba ni pe awọn to ba maa jẹ anfaani yoo tun ni nọmba idanimọ ile ifowopamọ, iyẹn Biometric Verification Number (BVN) ati foonu alagbeka.

Ẹdun ni eyi ni lati rii pe owo naa de ọdọ awọn ti ijọba ni lerongba, ki magomago ma si lọ wọnu eto ọhun.

O tẹsiwaju pe apapọ owo ti idile kọọkan yoo gba jẹ ẹgbẹrun marundinlọgọrin (N75,000) naira.

“Ẹgbẹrun marundinlọgbọn ni idile kọọkan yoo gba laarin oṣu kan, idile kan si gbọdọ ni eeyan marun-un, ki eto naa le kari fun oṣu mẹta. Idile miliọnu mẹẹdogun ni yoo gba owo yii fun oṣu mẹta, eyi ti apapọ rẹ jẹ idile marundinlọgọrin.”

Yatọ si eyi, Minisita fọrọ eto iṣuna tun ṣalaye siwaju pe ijọba tun fẹẹ ṣe iranwọ fawọn oniṣẹ ọwọ, oniṣowo, ọdọ, olokoowo kekeeke, awọn obinrin ati awọn oni worobo.

O ni ẹgbẹrun lọna aadọta (N50,000) naira ni awọn wọnyi yoo gba gẹgẹ bi owo iranwọ ti wọn ko si ni da a pada.

Sibẹ, ilana igbalode ni wọn yoo fi ṣe akọsilẹ awọn ti yoo jẹ anfaani, to fi jẹ pe eeyan ti ko din ni ẹgbẹrun kan lo maa lanfaani ni ijọba ibilẹ 774 to wa kaakiri Naijiria.

Aadọta biliọnu ni ijọba ya sọtọ fun eto yii.

Ẹdun ni ọna to dara leyi lati fi ṣe iranwọ faraalu lasiko yii.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here