Adájọ́ kò gba ìdírẹ̀ẹ́bẹ̀ Udom tó gún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n Kiríkirì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìlú tí kò sófin,ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀ làwọn àgbà wí.
Iwájú Onídàájọ Oyindamọla Ọgala, tilé-ẹjọ́ gíga kan tó wà nílùú Ikeja, ní ìpínlẹ̀ Èkó, ni wọ́n wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Udom, tó gún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa lọ. Ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìwà ọ̀daràn ni Agbèfọ́ba, Ọ̀gbẹ́ni Ọla Azeez, tó fojú olùjẹ́jọ́ balé-ẹjọ́ fi kàn án ní kóòtù.
Oun tí a gbọ́ ni pé ọ̀rọ̀ kékeré kan ló dija sílẹ̀ láàrin Udom ati Olóògbé Moses Joseph, lọ́jọ́ kẹrin, oṣù Kọkànlá, ọdún 2022, nílùú Igando, ní ìpínlẹ̀ Èkó. Káwọn èèyàn ṣì tóó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, Udom ti fọ̀bẹ gún ẹni kejì rẹ̀ tí wọ́n jọ ń jà pa pátápátá. Látìgbà náà sì lẹjọ rẹ̀ ti wà ní kóòtù, kó tóó di pé wọ́n ṣẹjọ́ rẹ̀ l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 yìí.
Nígbà tó máa sọ̀rọ̀, olujẹjọ lóun kò jẹbi gbogbo ẹ̀sùn tí agbèfọ́ba fi kan òun rárá.
Adájọ́ ilé-ẹjọ́ ọ̀hún ní kí wọ́n da Udom padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kiríkirì tó wà nílùú Èkó, lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ sí ọjọ́ kẹrin, oṣù Kẹta, ọdún 2024 yìí.