Ikú gbígbóná! Bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ márùn-ún jóná kú mọ́nú ilé
Fẹ́mi Akínṣọlá
À fi kí ààbò Ẹlẹ́dàá ṣáà má a dájú lórí i wa tẹbítará.
Kò sẹni tó máa gbọ́ bí iná ṣe run odidi ìdílé kan pátápátá tí omijé kò ní í dà pòròpòrò lójú èèyàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìbànújẹ́ ọ̀hún wáyé lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ kẹrìnlá, oṣù Kìn-ín-ní, ọdún 2024 yìí, lágbègbè Tudun-Wada, ní ìjọba ìbílẹ̀ Wada-Bompai, ní ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Bàbá, ìyá àt’àwọn ọmọ márùn-ún tí wọ́n wà nínú ilé ọ̀hún ni wọ́n kú kó tó di pé wọ́n gbé wọn dé ilé ìwòsàn ìjọba tó wà lágbègbè náà fún ìtọ́jú.
Òun tí a gbọ́ ni pé àṣáálẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù yìí, ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún wáyé, ati pé ojú oorun ni iná ọ̀hún ká gbogbo wọn mọ́. Káwọn aráalé àti àwọn aráàdúgbò sì tóó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, kò sẹ́ni tó lè sún mọ́ iná ọ̀hún, nítorí tó ti fẹjú gidi.
Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ panápaná agbègbè Dakata, Alhaji Saminu Abdullah, tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún múlẹ̀ fáwọn oníròyìn lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kín-ín-ní, ọdún 2024 yìí, sọ pé aráàlú kan tó n jẹ́ Ibrahim Sani, ló pe iléeṣẹ́ àwọn láṣàálẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún wáyé, táwọn sì sáré lọ síbẹ̀.
Ó ní nígbà táwọn débẹ̀, àwọn gbé bàbá, ìyá àt’àwọn ọmọ wọn márùn-ún kan táwọn bá nínú ilé náà jáde, táwọn si sáré gbé gbogbo wọn lọ síléèwòsàn fún ìtọjú, ṣùgbọ́n àwọn dókítà sọ pé òkú àwọn èèyàn náà làwọn gbé wá síléèwòsàn yii.
Ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn gbangba pé nígbà táwọn ilé iṣẹ́ NEPA agbègbè náà múná wọn dé lójijì ni iná burúkú ọ̀hún ṣẹ yọ lójijì nínú ilé àwọn olóògbé náà, ṣùgbọ́n nítorí pé ojú oorun ló bá wọn ní wọn kò ṣe mọ ibi tí wọn á sá sí tàbí bí wọn á ṣe tètè paná ọ̀hún kó tóó di ohun ńlá mọ́ wọn lọ́wọ́.
Àwọn dókítà ní èéfín iná tí ọkọọkan àwọn èèyàn ọhún fà símú gan-an ló ṣokùnfà bí wọ́n ṣe kú lẹ́ẹ̀kan náà