Ṣùrútù ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ olóògbé Akérédolú bínú sáwọn akọ̀rọ̀yìn

Ṣùrútù ṣẹlẹ̀ àwọn ọmọ olóògbé Akérédolú bínú sáwọn akọ̀rọ̀yìn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ẹnjinníà Ṣèyí Mákindé, àti akẹgbẹ́ ẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq, ti ṣàbẹ̀wò sí ìdílé Olóògbé Rótìmí Akérédolú, Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó tó jáde láyé.

Àbẹwò ọ̀hún, èyí tí wọ́n ṣe sílé Akérédolú, tó wà ní Idi-Iṣin, ládùúgbò Jericho, n’Ibadan, láti bá ìyàwó, àwọn ọmọ àti gbogbo mọlẹbi Gómìnà tó jáde láyé náà kẹ́dùn ló wáyé l’Ọjọ́rùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023.

Ṣùgbọ́n aáwọ̀ kan ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Gómìnà tó dolóògbé náà pẹ̀lú àwọn oníròyìn tó lọ síbẹ̀ láti mójútó ohun tó ń lọ.

Nígbà tí àwọn oníròyìn tẹlé àwọn Gómìnà méjèèjì náà wọnú ọgbà ilé ọ̀hún , níṣe làwọn ọmọ olóògbé fa ìbínú yọ, wọ́n ní kí àwọn oníròyìn jáde nínú ilé àwọn kíákíá, nítorí ilé tí Akérédolú fowó ara rẹ̀ kọ lèyí, kì í ṣe ilé ìjọba ti ẹnikẹ́ni kàn lè máa wọ̀ bó bá ṣe fẹ́.

Àwọn kan nínú ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ olóògbé ni wọ́n pẹ̀tù sí àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú, tí ọ̀rọ̀ náà kò fi di wàhálà ńlá.

Ariwo èdè àìyédè yìí ló jọ pé àwọn Gómìnà méjèèjì gbọ́ tí wọ́n fi yára jáde kúrò nínú ọgbà ilé náà láti bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ .

Gómìnà Abdulrazak, tó ṣàbẹ̀wò ọ̀hún lórúkọ gbogbo Gómìnà Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bíi alága ìgbìmọ̀ wọn lórílẹ̀-èdè yìí, ṣàpèjúwe ikú Akérédolú gẹ́gẹ́ bíi ìṣẹ̀l ìbànújẹ ńlá.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, Ẹnjnníà Mákindé tí í ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ṣàpèjúwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú rere tó ní ìgboyà láti jà fún ààbò àwọn aráàlú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, “ èmi gẹ́gẹ́ bíi ẹnìkan, àdánù ńlá ni ikú Arákùnrin Akérédolú jẹ́ fún mi, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan la ti jọ ṣe papọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rẹ́ àti tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Nígbà tá a dá àjọ elétò ààbò Àmọ̀tẹ́kùn sílẹ̀ , ipa takuntakun ni wọ́n kó lórí ọ̀rọ̀ yẹn.

“Bákan náà l’Arákùnrin Akérédolú kópa pàtàkì nígbà tí à n jà fún pé kí ipò Ààrẹ wá sí apá Ìwọ̀-oòrùn Gúúsù orílẹ-èdè yìí, àwọn pẹ̀lú Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra nígbà kan rí ni wọ́n jọ darí ìpàdé náà nílé ìjọba.

“ Wọ́n (Akeredolu) jẹ́ onígboyà èèyàn. Wọn kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, bí ọ̀rọ̀ bá ṣe rí lọ́kàn wọn ni wọ́n máa sọ ọ́. Ó kàn jẹ́ pé inú èèyàn kò lè dùn pé kí ẹni tí èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí kú ni, ọpẹ́ ló yẹ ká máa dá fún Ọlọ́run nítorí ipa rere tí wọ́n kó láyé àwọn èèyàn kan, àti fún ìdàgbàsókè àwùjọ”.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here