Ghali Na’Abba,olórí àwọn aṣọ̀fin tẹ́lẹ̀, jáde láyé

Ghali Na’Abba,olórí àwọn aṣọ̀fin tẹ́lẹ̀, jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Baà kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Lásìkò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń dárò ikú Olóògbé Oluwarotimi Akérédolú tí i ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, èyí tó ṣẹlẹ̀ láfẹ̀ẹ̀mọ́jú Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtàdílọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023 yìí, èèkàn olóṣèlú apá Òkè-ọya ilẹ̀ wa tó jẹ́ olórí àwọn ọmọléègbìmọ aṣojú-ṣòfin l’Abuja tẹ́lẹ̀, Alaaji Ghali Na’Abba, náà tún ti kí ayé pé ó dìgbòóṣe.

A gbọ́ pé òwúrọ̀ ọjọ́ Wẹ́sìdeè yìí kan náà ni ọkùnrin ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin (65) yìí mí èémí ìkẹyìn ní ọsibítù kan nílùú Àbùjá, tí i ṣe olú-ìlú ilẹ̀ wa.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣe sọ ọ́ di mímọ̀, wọ́n lo ti ṣe díẹ̀ tí àìsàn burúkú kan ti ń bá Na’Abba fínra, kí gbogbo ẹ̀ tó wáá já síkú yìí. Ìgbà kan wà tí wọ́n gbé bàbá náà lọ sílùú òyìnbó fún ìtọ́jú. Ọ̀pọ̀ oṣù ló sì fi wà lọhun-un, níbi tí wọ́n ti fún un ní ìtọjú tó péye, ìgbà tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ló padà sílé.

Àmọ́ lẹnu àìpẹ yìí ni àárẹ̀ mí-ìn tún ta lé olórí àwọn aṣòfin tẹ́lẹ̀rí yìí, èyí tó yọrí sí ikú rẹ̀.

Ẹ ò rántí pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, ni Alagba Ghali Na’Abba, ọdún 1999 tí ètò òṣèlú dẹ̀mókírésì ẹlẹ́ẹ̀kẹrin bẹ̀rẹ̀ ni ọkùnrin náà gbáàpótí ìbò, tó sì wọlé sípò aṣojú-ṣòfin Kano Municipal Federal Constituency, nígbà tí Olóyè Oluṣẹgun Ọbasanjọ di Ààrẹ ilẹ̀ wa.

Gẹ́rẹ́ tí wọ́n yọ Olórí àwọn aṣojú-ṣòfin ìgbà náà, Salisu Buhari, nípò, lórí ọ̀rọ̀ ìwé ẹ̀rí Fásitì Toronto rẹ̀ tó jẹ́ ayédèrú ni Na’Abba di olórí àwọn aṣojú-ṣòfin, ó sì wà nípò náà láti 1999 títí di ọdún 2023, tí ètò ìdìbò mí-ìn wáyé.

Ilé ẹ̀kọ́ Fásitì Ahmadu Bello, tó wà ní Zaria, ni olóògbé yìí ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òṣèlú lọ́dún 1979.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here