Ayedatiwa Gómìnà tuntun ìpínlẹ̀ Òǹdó, kéde àwọn tí yóó bá a ṣiṣẹ́ pọ̀

Ayedatiwa Gómìnà tuntun ìpínlẹ̀ Òǹdó, kéde àwọn tí yóó bá a ṣiṣẹ́ pọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ó jọ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àwọn àgbà tó sọ pé ẹni tó ṣojú kò dà bíi ẹni tó ṣẹ̀yìn, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọnarébù Lucky Orimisan Ayédatiwa, ti kéde odidi ọjọ́ mẹ́ta gbáko láti fi ṣọ̀fọ̀ ikú ọ̀gá rẹ̀, Arákùnrin Rótìmí Akérédolú, ẹni tó jáde láyé l’Ọ́jọ́rùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún yìí.

Ayédatiwa ṣe ìkéde yìí lásìkò tí wọ́n ń búra fún un gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tuntun lọ́fíìsì ìjọba tó wà ní Alagbaka, nílùú Akurẹ, ní nǹkan bíi aago márùn-ún kọjá ìṣẹ́jú mẹrìnlá l’Ọjọrùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2023.

Nínú ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ rẹ̀ ní kété tó gba èèkù idà ìṣàkóso, Ayedatiwa ni pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn lòun fi ń tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ńlá tó yí kan òun nítorí ikú tó wọlé mú ọ̀gá òun lọ lójijì.

Ó ní òun bá gbogbo ẹbí Akérédolú, Ọlọ́wọ̀ tìlú Ọ̀wọ̀, Ọba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye, àti gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ Òǹdó pátápátá kẹ́dùn lórí ikú ẹni wọn tó lọ.

Lára àwọn tó wà ní kàlẹ̀ lásìkò ìbúra wọṣẹ́ ọ̀hún ni: Olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọnarebu Ọlamide Ọladiji, Akọ̀wé ìjọba, Abilékọ Ọladunni Odu, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ade Adetimẹhin, àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aṣèjọba àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC.

Ó ní àdánù ńlá ni ikú Aketi jẹ́ fóun, nítorí láti ọdún 2012 ni àwọn ti jọ wà, ìyẹn lásìkò tó kọkọ gbé àpótí láti díje dupò Gómìnà, bó ṣe fìdí rẹmi nígbà náà ló ní kòdí àjọṣepọ̀ àwọn lọ́wọ́ rárá pẹ̀lú bí àwọn tún ṣe jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ fún àṣeyọrí rẹ̀ lọ́dún 2016, tó sì jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà fún ìgbà àkọ́kọ́ .

Ó ní ṣe làwọn jọ wà títí kó tóó wá mú òun gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ lọdún 2020, lásìkò tó ń díje fún sáà kejì.

Gómìnà tuntun yìí ní kò sí àní -àní pé Aketi ti fipa rere lélẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó ṣe ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, tí òun náà sì ṣetán láti tẹ̀síwájú níbi tí ọ̀gá òun bá iṣẹ́ dé.

Ó rọ gbogbo àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Òǹdó láti ṣàtìlẹ́yìn fún òun, kí wọ́n sì tún máa gbàdúrà fún òun, kí iṣẹ́ náà baà lè túbọ̀ rọrùn láti ṣe.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí Gómìnà Lucky Ayedatiwa gba èèkù idà ìṣàkóso ìpínlẹ̀ Òǹdó ló ti kéde ìyànsípò àwọn èèyàn kan gẹ́gẹ́bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀.

Ní ìbámu pẹ̀lú àtẹ̀jáde tí Ìgbákejì olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Òǹdó, Ọmọkùnrin Sẹgun, fi síta lálẹ́ Ọjọ́rùú, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejiìlá, ọdún 2023 yìí, ó ní Gómìnà ti fọwọ́ sí ìyànsípò àwọn èèyàn wọ̀nyí, tí iṣẹ́ wọn sì gbọdọ̀ bẹ̀rẹ̀ lẹ́yẹ-ò-sọkà.

Àwọn márùn-ún tí wọ́n kéde ìyànsípò wọn ni: Ọmọọba Ebenezer Adeniyan, ẹni tí yóó jẹ́ Akọ̀wé ìròyìn tuntun fún Gómìnà Ayédatiwa, Ọ̀gbẹ́ni Smart Ọmọdunbi, Olùbádámọ̀ràn fún gómìnà lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, àti Abire Sunday Olugbenga, Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀rọ ayélujára.

Àwọn yòókù ni, Omidan Motunrayọ Oyedele, Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún fọ́tò yíyà, àti Dókítà Temitayọ Iperepolu, ẹni tí yóó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Gómìnà nílé ìjọba.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here