Ó mà ṣe o, Gómìnà Rótìmí Akérédolú ti f’ayé sílẹ̀ o!

Ó mà ṣe o, Gómìnà Rótìmí Akérédolú ti f’ayé sílẹ̀ o!

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báa kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè, ikú ti ṣíwọ́ ọ Gómìnà Akérédolú kúò ní dúníyàn.
Ohun tí a gbọ́ ni pé ìlú Èkó ni Gómìnà náà dákẹ sí l’Ọjọ́rùú, ọjọ́ kẹtadínlógún, oṣù yìí, lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínáàádọ́rin.

Àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ ló ti dá Gómìnà náà gúnlẹ fún ìgbà pípẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbé e lọ sílùú Òyìnbó fún ìtọ́jú, inú oṣù Kẹsàn-án án ni wọ́n dá a padà wá sílé. Ilé rẹ̀ tó wà nílùú Ìbàdàn ni Arákùnrin sì wà láti ìgbà náà tí wọ́n ti ń tọjú rẹ̀.

Kìí ṣe pé ara Gómìnà náà ti yá tí wọ́n fi gbé e wá láti ìlú Òyìnbó, ṣùgbọ́n nítorí pé àìsàn tí kò ṣeé wò, àfi ìdásí Ọlọ́run nìkan, ló ń ṣe é ló jọ pé ó mú kí wọ́n máa gbé e bọ wá sílé láti Oke-Okun. Látìgbà náà ló ti wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí kò sí lè padà sí ìpínlẹ̀ Òǹdó tó ti ń ṣèjọba.

Àìyá ara Arákùnrin ṣàkóbá fún ètò ìjọba ìpínlẹ̀ Òǹdó, nítorí pé kò gbé ìjọba fún igbákejì rẹ̀ nígbà tó kọkọ dé. Bó ṣe ti ìlú Òyìnbó dé ló ní ara òun ti yá, òun sì fẹ́ máa bá ìṣèjọba òun lọ. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n ń ṣàtìlẹ́yìn fún un ni wọ́n ń ṣe ìjọba náà, tí wọ́n sì ń fẹ̀sùn kàn wọ́n pè wọ́n ń fi ayédèrú ìbuwọlù Gómìnà gbé òbítíbitì owó jáde lásùn wọn ìjọba.

Láìpẹ́ yìí ni Gómìnà náà kọ̀wé sáwọn aṣòfin pé òun fẹ́ lọ gba ìtọjú nílùú Òyìnbó, èyí tó mú kó gbé ìjọba fún igbákejì rẹ̀, Lucky Ayedatiwa, pe kó máa bá ìṣàkóso ìjọba lọ, ìyẹn lẹ́yìn tí Ààrẹ Bọla Tinubu ti pàṣẹ fún un pé kò kọwe láti gbé ìṣàkóso ìjọba náà fún igbákejì rẹ̀.

Ṣùgbọ́n ipò tí ọkùnrin náà wà kò lè jẹ́ kí wọn gbé e lọ sílùú òyìnbó nítorí àìlera náà ti wọ̀ ọ lára gidigidi. Èyí la gbọ́ pé ó mú kí wọ́n gbé e lọ sí ọsibítù kan nílùú Èkó, tí wọ́n ti ń tọjú rẹ̀, kó tó di pé àìsàn náà le sí i, ti wọ́n sì ń wá gbogbo ọnà láti rí i pé ó rí ìtọjú gidi gbà, ṣùgbọ́n ó ṣe ni láàánú pé iléèwòsàn tí wọ́n kò dárúkọ náà ni Akérédolú padà dakẹ sí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here