Mo mọ ẹni tó pa ẹ̀gbọ́n mi–Àbúrò Mohbad
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán,èèyàn ńlá ò ní-ín sinmi.
Adura Alọba, tí í ṣe àbúrò àti ọmọ tí wọ́n bí lé olóògbé Ilerioluwa Alọba, táwọn èèyàn mọ̀ sí Mohbad, ti dárúkọ ẹni tó ní ó dá òun lójú pé ó pa bọ̀ọ̀dá òun.
Níwájú àwọn ìgbìmọ̀ tí wọ́n ń wádìí ikú tó pa Mohbad, nílé-ẹjọ́ tó wà ní agbègbè Ita-Ẹlẹwa, Ikorodu, ní ìpínlẹ̀ Èkó, ni Adura ti là á mọ́lẹ̀ pé ọ̀rẹ́ àti kékeré ni ẹgbọn òun, àti ẹni tí wọ́n ń pè ní Primeboy, tó gbẹ̀mí Mohbad.
“Àbúrò Mohbad gangan ni mi. Ọmọ ogún ọdún ni èmi. Òun ni ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì, nígbà ti èmi jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹta. Ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi àtìyàwó rẹ̀ ni mo ń gbé. Wọ́n máa ń jà gan-an nínú ilé, lọ́pọ̀ ìgbà sì níyì, bàbá mi ló máa ń wá bá wọn yanjú ẹ. Wọ́n tún ja ìjà kan ṣaájú eré tí Mohbad ṣe kẹ́yìn nílùú Ikorodu, àmọ́ èmi ò sí níbẹ̀ nígbà tóun àti Primeboy ń jà. Wumi ló padà sọ fún mi pé wọ́n jà. Tí wọn bá ní kí n mú olórí afurasí lórí ẹni tó pa ẹ̀gbọ́n mi, Primeboy ni.
“ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí níbẹ̀ lásìkò tí wọ́n jà, gbogbo bi ọ̀rọ̀ ṣe lọ ni Wumi ṣàlàyé fún mi pátá, mo sì gbà á gbọ́ . Nígbà tá a délé lẹ́yìn eré tó lọ ṣe, ìsàlẹ̀ lèmi wà nígbà tí gbogbo wọn ti gòkè lọ. Nígbà tó yá tí mo fẹ́ lọ fún ẹ̀gbọ́n mi ní fóònù rẹ̀ nínú yàrá rẹ̀, orí ariwo àti àríyànjiyàn ni mo bá àwọn àtìyàwó wọn nítorí fìsà Canada.
“ Kí nọ́ọ̀sì tó wá rárá, gágá ni ara bọ̀ọ̀dá mi yá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rí ipa ẹ̀jẹ̀ ní ẹgbẹ́ ìgúnpá rẹ̀ lọ́jọ́ Túsìdeè. Èmi ni mo ṣe Indomie tí gbogbo wá jẹ lọ́jọ́ náà. Lórí ọ̀rọ̀ pé ẹ̀gbọ́n mi ní àrùn ọpọlọ, irọ́ pátá gbáà ni o. Kokooko lara rẹ̀ le, kò sì sí ọ̀rọ̀ pé ó ti ní gán-án-gàn-àn-gán rí. Primeboy ló pa ẹ̀gbọ́n mi o”.
Atótónu Adura, àbúrò Mohbad nìyí níwájú àwọn tó n ṣèwádìí ikú ẹ̀gbọ́n rẹ̀.