Ààrẹ Tinubu dá sí aáwọ̀ láàrin Akeredolu àti Aiyedatiwa

Ààrẹ Tinubu dá sí aáwọ̀ láàrin Akeredolu àti Aiyedatiwa

Fẹ́mi Akínṣọlá

Bí kò bá sí ìyípadà kankan ó ṣeéṣe kí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu ti yanjú aawọ tó ń wáyé láàrin Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Arakunrin Rotimi Akeredolu àti igbákejì rẹ̀, Lucky Aiyedatiwa.

Ojútùú sí ọ̀rọ̀ yí kò ṣẹ̀yìn ìpàdé kan tí Ààrẹ ṣe nílé ìjọba lAbuja lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì ọ̀sẹ̀ yìí níbi tí Ààrẹ ti ní kí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà gbérù gba àlàáfíà láàyè.

Níbi ìpàdé náà la ti rí Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Òǹdó, Ọladiji Ọlamide, igbákejì Gómìnà Òǹdó, Lucky Aiyedatiwa, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC Abdullahi Umar Ganduje.

Níbi ìpàdé yí sì ni olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ti kéde pé àwọn ti dáwọ ìgbésẹ̀ àti yọ Aiyedatiwa nípò dúró.

Èyí wáyé lẹ́yìn àfẹnukò wọn níbi ìpàdé náà tó gbà wọ́n tó wákàtí mẹ́fà.

Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Òǹdó tó ka àbájáde ìpàdé àlàáfíà náà se , tí àwọn akọroyin ṣàlàyé pé, ’’Àkọ́kọ́, a máa gba àlàáfíà láàyè, ìkejì, a kò ní í túlé ká mọ, igbákejì Gómìnà yóó máa bá iṣẹ́ lọ gẹ́gẹ́ bí àfẹnukò ilé aṣòfin ’’

Yàtọ̀ sí pé Ààrẹ ní kí wọ́n dáwọ ìyọni nípò igbákejì Gómìnà Aiyedatiwa dúró, Ààrẹ tún pàṣẹ pé kí Aiyedatiwa máa bá ìṣàkóso ìpínlẹ̀ náà lọ títí tí Gómìnà Akérédolú yóó fi padà sípò.

Bẹ́ẹ̀ náà ló sọ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n kó dí ẹnu ọnà ilé aṣòfin kúrò ní kíákíá.

Ìyanjú aáwọ̀ yí lọ́jó Ẹtì wáyé lẹ́yìn nǹkan bí ọjọ́ méjì tí àwọn àgbààgbà ipinlẹ Ondo késí aarẹ pe ki o tara dásí ọ̀rọ̀ awuyewuye Ondo yìí kí ó má baà fa ìdẹnukọlẹ̀ ìṣèjọba.

Wọ́n tún késí adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kí wọ́n ṣe ìtọ́sọ́nà fáwọn tí ọ̀rọ̀ kan kí oníkálùkù baà lè tọwọ́ ọmọ rẹ̀ bọ aṣọ.

Nínú ìwé tí wọ́n kọ sí Ààrẹ, àwọn tó ṣagbátẹrù ọ̀rọ̀ yí, Reuben Fasoranti àti akọ̀wé Bakkita Bello rọ àwọn ilé aṣòfin láti má ṣe yọ Gómìnà tàbí igbákejì rẹ̀ nípò.

Láti ìgbà tí Gómìnà Akeredolu padà dé láti ìrìnàjò níbi tó ti lọ gba ìtọjú ni wàhálà ti bẹ̀ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ nínú oṣù kẹ̀sán ni Akeredolu padà dé sí Nàìjíríà lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tó sì ti ń ṣe àkóso ìjọba láti ìlú Ìbàdàn tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here