Àwọn òsìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun àtàwọn ọlọ́pàá gbéná wojú ara wọn

Àwọn òsìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun àtàwọn ọlọ́pàá gbéná wojú ara wọn

Fẹ́mi Akínṣọlá

Lónìí ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá ọdún 2023, laàkókò tí àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga tí ìpínlẹ̀ Osun fẹ́ ṣe ìpàdé pọ pẹ̀lú àwọn Adájọ́ ni àwọn ọlọ́pàá da gáàsì tajútajú bolẹ̀

Bí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga tí ìpínlẹ̀ Osun ṣe n ṣe ìfẹ̀hónúhàn láti má fi ààye gba Adájọ́ó Àgbà Adepele Ojo láti wọ ọ́fíìsì rẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

Àwọn ọlọ́pàá fi gáàsì tajútajú lé àwọn òṣìṣẹ́ náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn sì fara pa pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn to lọ síbẹ̀ pẹlu.

Nígbà tí ẹnì to jẹ́ alága àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga náà, Olugbenga Olakunle Eludire ba àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, sọ pe ẹtọ awọn làwọn ń bèèrè fún.

Eludire ni “Ẹ̀tọ́ wa lawá bèèrè lọ́wọ́ Adájọ́ Àgbà Adepele Ojo tí àwọn èèyàn wa sì ṣe ìfehónúhàn lórí ẹ̀tọ́ àwọn.

Lójijì ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá yà de tí wọ́n sì fi gáàsì tajútajú lé wa pẹ̀lú kòbókò tí ọ̀pọ̀ sì farapa yánnayànna.”

Eludire ni àwọn ìgbìmò kan lára àwọn Adájọ́ ló pè fún ìpàdé lórí ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́ náà kì àwọn ọlọ́pàá tó tẹ̀lé Adájọ́ àgbà Adepele tó fìyà jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn.

“Oun tí àwa òṣìṣẹ́ bèẹrè lọ́wọ́ Adájọ́ Àgbà Adepele Ojo ni pé kó dá àwọn òṣìṣẹ́ tó tí fún ní ìwé ìdádúró lẹ́nu isẹ́ padà àti àwọn ẹ̀tọ́ wọn.”

Ní báyìí ẹni tó jẹ́ Alága fún àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga tí ipínlẹ̀ Osun, Olugbenga Olakunle Eludire tí kéde ìdasẹ́sílẹ̀ títí ìgbà tí Adájọ́ Àgbà Adepele Ojo yóó fi san gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ wọn .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here