A máa kàńpá fún INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára – Ilé aṣòfin àgbà

A máa kàńpá fún INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára – Ilé aṣòfin àgbà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ìdìbò nílé aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti ní àwọn máa gbé òfin kalẹ̀ láti pọ́n ní dandan fún àjọ tó ń rí sí ètò Nàìjíríà, INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára lásìkò ìbò.

Alága ìgbìmọ̀ náà, Aṣòfin Sharafadeen Alli ló sọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń bá Iléeṣẹ́ ìròyìn Channels TV sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

Alli ní òfin tó wà nílẹ̀ báyìí kò ṣe é ní dandan fún INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára àmọ́ tí àwọn ti ń gbèrò láti yí òfin náà padà.

Ó ní ọ̀kan lára ètò tí ìgbìmọ̀ àwọn fẹ́ gbájúmọ́ nìyí tó fi mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ mọ́ ètò ìdìbò mìíràn.

Ó fi kún un pé àwọn tún ń mójútó láti ri pé gbogbo ẹ̀sùn tó máa ń wáyé ṣáájú ètò ìdìbò ni ilé ẹjọ́ yanjú kí ètò ìdìbò gangan tó wáyé.

Aṣòfin náà ni èyí máa mú àdínkù bá bí àwọn awuyewuye tó yẹ kó ti parí ṣáájú ètò ìdìbò ṣe máa ń wólẹ̀.

Bákan náà ló fi kun pé àwọn tún ń gbèrò láti rí pé gbogbo ẹ̀hónú tó ń wáyé lẹ́yìn ìdìbò ni ilé ẹjọ́ parí ṣáájú kí wọ́n tó búra wọlé fún ẹni tí ìlú bá yàn.

Ó ní èyí máa mú àdínkù bá bí ètò ìdìbò ṣe máa ń wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ kan lẹ́yìn ètò ìdìbò gbogbogbo.

Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ohun èlò ẹ̀rọ̀ INEC ni àwọn tún ń gbèrò láti ṣe àmójútó rẹ̀ nítorí ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn pé IReV kò ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ lásìkò ìbò tó kọjá.

Alli ni àwọn máa mójútó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kí àsìkò ìbò mìíràn tó gbéra sọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here