Àwọn kan ń gbèrò láti ṣèkọlù sáwọn ilé ìtura ńlá ní Nàìjíríà – Amẹ́ríkà ṣèkìlọ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ilé iṣẹ́ aṣojú ilẹ̀ America tó wà lorilẹ-ede Nàìjíríà ló ti fi léde pé àwọn kan ń gbìmo láti ṣe akọlu sáwọn ilé ìtura tó lórúkọ láwọn ìlú nla-nla káàkiri Nàìjíríà.
Nínú atẹjade kan tí ilé aṣojú náà fi sórí ìkànnì ayélujára wọn lọjo Ẹtì ọjọ́ kẹta oṣù kọkànlá ni wọ́n ti wí pé “ilẹ ní ẹri tó dájú pé ìpinnu àkọlù sáwọn ilé ìtura kan ní Nàìjíríà ló ti dé ààyè tó lápẹẹrẹ”.
Àtẹ̀jáde náà fikún pé àmọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò nílẹ̀ Nàìjíríà ń sa gbogbo ipá wọn láti dènà àkọlù ọ̀hún.
Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti gba àwọn ọmọ ìlú náà tó wà ní Nàìjíríà lámọ̀ràn pé kí wọ́n ronú dáadáa lórí ìkìlọ̀ yìí kí wọn tó gba iyàrá tàbí lọ̀ọ́ gbafẹ́ nílé ìtura tó bá lókìkí ní Nàìjíríà.
Wọ́n sì tún fi nọ́mbà ẹ̀rọ ìléwọ́ tí wọ́n lè pè nígbàkúùgbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro léde.
Bákan náà ni ìjọba Améríkà tún kìlọ̀ fáwọn ọmọ ilẹ̀ náà láti máa wo àyíká wọ́n fínífíní láwọn ilé-ìtura tó lààmì-laaka kí wọ́n sì tún tẹlé gbogbo ìlànà tí ìjọba là kalẹ̀ fún wọn lórí àbẹ̀wò sí Nàìjíríà.