A ti ṣetán àti dá $150m tí Abacha jí kó padà fún Nàìjíríà – Ìjọba France

A ti ṣetán àti dá $150m tí Abacha jí kó padà fún Nàìjíríà – Ìjọba France

Fẹ́mi Akínṣọlá

Òkú ọ̀run kò yé nawọ́ àánú sí Orílẹ̀ yìí láti bíi ọdún díẹ̀ sẹ̀yìn. Òmíràn tún ni ti Orílẹ̀-èdè France yìí tí wọ́n ti ṣetán láti dá owó tí iye reẹ̀ tó àádọ́jọ mílíọ̀nù pọ́ùn padà fún ìjọba Nàìjíríà, èyí jẹ́ lára owó tí Ààrẹ Ológun Nàìjíríà nígbà kan rí, Sani Abacha jí kó lọ síbẹ̀.

Agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu, Ajuri Ngelale, ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nínú àtẹ̀jáde kan.

Ngelale ní Ààrẹ Bola Tinubu ti kan sáárá sí ìjọba France fún ìgbésẹ̀ láti dá owó náà padà fún Nàìjíríà.

Lásìkò tó ń gbàlejò Mínísítà oríleẹ̀-èdè France fún ileẹ̀ òkèèrè àti ilẹ̀ Yuroopu, Catherine Colonna, Ààrẹ Tinubu kan sárá látàrí ìrẹ́pọ̀ àti ìbáṣepọ̀ tó gún régé tó ń wáyé láàrin oríleẹ̀-èdè méjèèjì, èyí tó ń wáyé lẹ́yìn àbẹ̀wò rẹ̀ sí France.

Tinubu ní “Adúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún dídá owó tí Abacha jí padà, a mọ rírì ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín lórí dídá owó Nàìjíríà padà.

“A ó lo owó náà fún ìdàgbàsókè Nàìjíríà .”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here