Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ dójú ikú, àwọn ẹbí akẹ́kọ̀ọ́ ń pè fún ìdájọ́ òdodo

Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ dójú ikú, àwọn ẹbí akẹ́kọ̀ọ́ ń pè fún ìdájọ́ òdodo

Fẹ́mi Akínṣọlá

A fi kí Ọlọ́run máa kówa yọ nínú ìgbésẹ̀ wa gbogbo. Àwọn ẹbí akẹ́kọ̀ọ́ ìpele kẹta ni ilé ẹ̀kọ́ girama àkọ́kọ́, Marwan Sambo tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ti ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ wọn.

Ìròyìn ní àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Al Azhar Academy ní Kaduna ni wọ́n na akẹ́kọ̀ọ́ tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀.

Ikú Marwan gba orí ayélujára káàkiri Nàìjíríà lẹ́yìn tí ìròyìn gbòde pé àwọn olùkọ́ ló na akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ náà títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna ní ẹkùn àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa tí wọ́n sì ti pè fún ìwádìí tó péye lórí ohun tó ṣokùnfà ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn fídíò àti àwòrán tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí àpá ṣe wà lára òkú Marwan èyí tó bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú.

Bàbá Marwan, Mallam Nuhu Sambo ní bí òun ṣe máa rí ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ òun ló jẹ òun lógún jùlọ báyìí.

“Ìdájọ́ òdodo la fẹ́ nítorí irú nǹkan báyìí kò yẹ kó máa wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ rárá.”

Bàbá Marwan ní oṣù márùn-ún sẹ́yìn ni òun fi ọmọ òun sí ilé ẹ̀kọ́ Al Azhar nítorí kò sí àyè ní ilé ẹ̀kọ́ tó wà tẹ́lẹ̀.

Ó ní àmọ́ dípò tó yẹ kí Marwan wọ kíláàsì àkọ́kọ́ fún ìpele kejì girama ìyẹn SS1, JSS 3 ni wọ́n gbà á sí.

“Èyí máa ń mu kí Marwan máa ṣe bákan bákan nítorí rẹ̀.”

“Kódà ní ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ló dé tí kò wá sí ilé ẹ̀kọ́, ó ní torí àwọn ẹgbẹ́ òun ti wà ní SS1 ṣùgbọ́n tí òun wà ní JSS3.

“Lẹ́yìn náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fìyà jẹ́.”

Rukayya Sambo tó jẹ́ ẹbí ìyá Marwan tó ti ń tọ́jú rẹ̀ láti kékeré lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ kú sọ fún akọroyin pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni màmá tó bí Marwan jáde láyé lẹ́yìn tó bí ìbejì.

Ó ní òun tó jẹ gbogbo àwọn lógún ni bí àwọn ṣe máa rí ìdájọ́ òdodo gbà lórí ikú Marwan kí àwọn ilé ẹ̀kọ́ mìíràn le ti ibẹ̀ kọ́gbọ́n.

“Ibi àlàáfíà ló yẹ kí ilé ẹ̀kọ́ jẹ́, tó yẹ kí àwọn ọmọ ti máa kọ́ nípa bí wọ́n ṣe mú àyípadà rere bá àwùjọ, kò yẹ kó jẹ́ ibi ìyà àti ikú.”

Ó fi kun pé Marwan kò sọ fún òun ri pé wọ́n máa ń fi ìyà jẹ òun nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn máa ń sọ pé wọ́n burú púpọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ náà.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kaduna ní gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ Al Azhar àti igbákejì rẹ̀ ti wà ní àhámọ́ àwọn.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kaduna, Mansir Hassan fìdí èyí múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó sì ní ìwádìí ń lọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ó ní àwọn afurasí méjì tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ni àwọn ti ń fi ọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò.

Ó fi kun pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kaduna ti pè fún ìwádìí tó lòòrìn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here