Adeleke fagi lé ìrìnàjò sí Òkè-Òkun fáwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Adeleke fagi lé ìrìnàjò sí Òkè-Òkun fáwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ ti di sọ́wóná báyìí o, bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Sẹ́ẹnétọ̀ Ademọla Adeleke, ti pàṣẹ pé títí tí ọdún 2023 tí a wà yìí yóò fi parí, kò sí ọ̀gá àgbà nínú iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà tó gbọdọ̀ rin-ìrìnàjò lọ sí òkè-òkun.

Ó ní ìgbésẹ yìí wáyé láti dín owó tí ijọba ń ná kù, kí ìjọba sì lè gbájú mọ́ àwọn iṣẹ́ àkànṣe tó yẹ láti ṣe, nítorí ìrètí àwọn aráàlú pọ̀ látọ̀dọ̀ ìjọba.

Lásìkò ìpàdé àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹlẹ́ẹ̀kejì irú ẹ tó wáyé nílùú Oṣogbo, lọjọ Tọ́sìdeè, ní Gómìnà ti ṣàlàyé pé gbogbo àwọn lọ́gàálọ́gàá náà ni wọ́n ní iṣẹ́ pàtàkì láti ṣe pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ lórí àgbékalẹ̀ ètò ìṣúná ọdún tó ń bọ̀.

Adeleke sọ síwájú pé ṣe ni kí àwọn lọ́gàálọ́gàá náà máa darapọ̀ mọ́ ìpàdé Òkè-òkun tí wọ́n bá ní nípasẹ̀ ìkànnì ayélujára.

Ó ní tí irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ bá wáá jẹ́ pàjáwìrì, tó sì pọn dandan fún irú ọ̀gá bẹ́ẹ̀ láti lọ, wọ́n ní láti gba àṣẹ latọdọ Gómìnà fúnra rẹ̀.

Bákan náà ni Adeleke tún sọ fún olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun níbi ìpàdé náà láti ṣe àkọsílẹ ojúṣe àwọn kọmíṣánnà àti àwọn olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà.

Adeleke pàṣẹ pé, láti àsìkò náà lọ, àwọn olùdámọ̀ràn pàtàkì gbọdọ̀ kọkọ máa fún àwọn Akọ̀wé-àgbà ní lẹ́tà tí wọ́n bá fẹ́ẹ́ fi ránṣẹ́ sí kọmíṣánà iléeṣẹ́ tí wọ́n wà.

Ó ní eléyìí yóó dènà ìwà ‘emi-ju-ọ, iwọ-o-ju-mi láàrin àwọn kọmíṣánnà àtàwọn olùdámọ̀ràn pàtàkì.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here