Ìdá mó̩kàndínló̩gó̩rùn-ún àwo̩n olùdámò̩ràn ayélujára kò rí ayé wo̩n tò – Yul Edochie
Mary Fágbohùn
Ogbontarigi osere tiata Naijiria, Yul Edochie ti se’kilo fun awon afenifere re sora fun imoran lati ori ayelujara eyi to toka si bii ti eni to n tiraka lati to ile aye won papo.
Edochie, eni to wa si abe adojuko ni opo igba lori ayelujara lati igba to ti se igbeyawo pelu iyawo re keji, Judy Austin; lo si ori Instagram re lati fi ikilo naa lede.
Osere naa gba awon afenifere re nimoran lati se ohun to ba sise fun won ati pe ki won dena imoran ti won ba ri lati ori ayelujara.
Edochie ko o pe, “Se e si n teti si imoran lati odo awon eniyan lori ayelujara? Mo rerin. Ida mokandinlogorun-un awon eniyan ti won n gba yin nimoran ko tii ri ona lati to igbesi aye won. Won o tii yanju isoro ebi won. Arakunrin, arabinrin, se o si n se bee. Se nnkan to ba sise fun e. Dojuko irinajo re.”