È̩sùn Yvonne Nelson fé̩rè̩ ba ìbásepò̩ èmi àti olólùfé̩ mi jé̩ – Iyanya
Olorin Naijiria, Iyanya Onoyom Mbuk, ti a mo si Iyanya, ti safihan pe esun ti orebinrin oun teleri omo Ghana, osere tiata Yvonne Nelson fi kan oun wi pe oun ni ibasepo miran pelu Tonto Dikeh fere je ki oun padanu ibasepo ti oun wa ninu re.
Olorin ‘Kukere’ naa so eyi di mimo nigba to farahan lori eto Tea With Tay laipe yi ti osere tiata, Temisan Emmanuel Ahwieh, ti a mo si Taymesan se atokun re.
E ranti pe Yvonne Nelson ninu iwe re, ‘I Am Not Yvonne Nelson’ to gbe jade ni ojo kejidinlogun osu keje, 2023, salaye nipa bi o se mo pe orekunrin re teleri, Iyanya, ni ibasepo miran pelu osere tiata, Tonto Dikeh.
Iyanya so pe leyin ti iwe naa jade, omobinrin kan ti oun n wa lati fe ko fe gba fun oun.
O wi pe, “Ohun to sele [esun Yvonne Nelson] fe dani lori ri, arakunrin. Isele naa fere mu ki n padanu ibasepo mi. Ibasepo ti mo wa ninu re bayii.
“Saaju iwe yi [iwe Yvonne Nelson], mo n ba omobinrin kan ti ko mo nnkankan ti ko si ni okiki soro sugbon lojiji iwe naa jade, gbogbo nnkan beere si ni gbon. Omobinrin naa wa so pe , ‘Omo, arakunrin yi, o ti yi pada? Se o daa loju pe iru eyi ko ni sele si mi?’”