Mi ò so̩ pé ìyàwó mi fé̩ mi nítorí owó’ – Julius Agwu
Mary Fágbohùn
Ogbontarigi osere tiata ati aderinposonu Julius Agwu ti se oro to so pe iyawo re teleri, Ibiere Maclayton, fe nitori owo.
E ranti pe ninu irohin kan lati ara iforo-wani-lenu-wo to se ni oro ti jade pe o soro lerefee pe iyawo oun teleri “fe oun nitori owo ti o wa lowo re ni igba naa.”
Amo sa, ninu oro to so ninu womi ki n wo o to se lori Instagram pelu atokun eto Daddy Freeze, Julius Agwu so pe oun ko so bee.
Daddy Freeze: “Won ni e so pe iyawo yin, IB, fe e yin nitori owo. E jowo, e soro lori re.”
Julius Agwu: “Iwe irohin Punch se iforo-wani-lenu-wo pelu mi. Mi o so nnkan to jo bee. Mo ri nnkan naa laipe, Segun Arinze fi ranse si mi.
“Mi o le ba ara mi je ni ona bee. Iyawo mi teleri ko fe mi nitori owo kankan. Ati pe Julius Agwu ko so bee. Iya awon omo mi ni. Mi o le so iru nnkan bee nipa re.”