Àìtètè rí àyè̩wò àìsàn ló pa Sound Sultan – 2Baba

Àìtètè rí àyè̩wò àìsàn ló pa Sound Sultan – 2Baba

Mary Fágbohùn

Ogbontarigi olorin Naijiria, Innocent Ujah Idibia, ti a mo si 2Baba, ti so pe ko ye ki ore oun ati olorin, Sound Sultan, eni ti arun jejere ona ofun se iku ni 2021 ku ka ni o tete mo nipa arun jejere naa.

O ni nigba ti olorin ‘Jagbajantis’ naa si wa lori idubule aisan, won ro pe ako iba ni.
O tun da eto ilera orile ede yi ti ko peye lebi fun aitete se awari aisan naa.

Ogbontarigi olorin naa farahan lori eto Afrobeats podcast laipe yi ti omo Britaini-Naijiria, Adesope Olajide, ti a mo si Shopsydoo se atokun re.

Atokun naa beere pe: “Bawo ni ibasepo re pelu Sound Sultan ati pe bawo ni ipadanu re se ri ni ara re?”

2Baba fesi pe: “O [Sound Sultan] je okan lara awon ti o ‘dara ju’, ti mo ba le lo oro naa. O je okan lara awon eniyan ti o ‘dara ju’ ti o le ba pade, bii Angeli.

“Fun igba pipe, mi o fe gba a mora, o dabi awada. Iwadii aisan naa pe. A ro pe ako iba lasan ni, o se ayewo ni Naijiria. Sugbon mi o fe wo inu gbogbo re.”

E ranti pe Sound Sultan jade laye ni United States ni ojo kokanla osu keje, 2021, ni eni odun merinlelogoji, laipe die ti won se awari aisan ti o ni bii jejere ona ofun (Angioimmunoblastic T-cell lymphoma)..

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here