Ìjọba àpapọ buwọ́lu N5bn owó ìrànwọ́ “palliative” fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti Abuja

Ìjọba àpapọ buwọ́lu N5bn owó ìrànwọ́ “palliative” fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan àti Abuja

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ-èdè Nàìjíríà ti buwọ́lù iye owó bílíọ̀nù márùn náírà fún ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó fi mọ́ olú ìlú orílẹ-èdè yìí ìyẹn ìlú Abùjá.

Ìjọba ní kí wọ́n fi owó yìí ra oúnjẹ láti pín fún àwọn tí kò rọ́wọ́ họrí ní gbogbo ìpínlẹ̀ kówá wọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babangana Zulum lo fi èyí léde ní ilé Ààrẹ nílùú Abùjá ní kété tí ìgbìmọ̀ aláṣẹ fún ètò ọ̀rọ̀ ajé parí ìpàdé níbẹ̀.

Lafikun sí ọrọ̀ owó yìí, Zulum ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ tún ṣe àgbékalẹ̀ àpò ìrẹsì tó kún ọkọ̀ akẹ́rù márùn fún gbogbo àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì.

Gómìnà Zulum ṣe é ní àlàyé wípé gbogbo Gómìnà kọ̀ọ̀kan ló gba àṣẹ láti ra àpò ìrẹsì ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ọ̀rún, àpò àgbàdo ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì àti ajílẹ̀.

Ó ní ìjọba fún wọn ní ìdá méjìléláàdọ́ta gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn owó àmọ́ ìdá méjìdíláàdọ́ta tó kù jẹ́ gẹ́gẹ́ bíi owóyàá.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here