DSS kòì túkùn lọ́rùn Emefiele, wọ́n ló lẹ́jọ́ tuntun láti jẹ́

DSS kòì túkùn lọ́rùn Emefiele, wọ́n ló lẹ́jọ́ tuntun láti jẹ́

Fẹ́mi Akínṣọlá
Iná ò tán láṣọ, ẹ̀jẹ̀ ò tán léèkáná lọ̀rọ̀ Ìjọba àpapọ̀ àti Emefiele
Ìjọba àpapọ̀ ti yọwọ́ nínú ẹjọ́ tí wọ́n pe Gómìnà tẹ́lẹ̀ fún báńkì àpapọ̀ Nàìjíríà,CBN Godwin Emefiele lórí ẹsùn “ níní ìbọn lọ́nà ti kò bá òfin mu ,èyí tí wọ́n pè é níwájú ilé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ tó wà nílùú Èkó.

Adarí àgbà iléeṣẹ́ ètò ìdájọ ni ìjọba àpapọ̀, Mohammed Abubakar ṣàlàyé nínú àrọwà àfẹnuṣe kan tó gbé kalẹ̀ níwájú ilé ẹjọ́ náà pé àwọn ń gbé ìgbésẹ̀ yìí nítorí àwọn èsì ìwádìí tuntun tó tẹ àwọn lọ́wọ́ .

Àmọ́ṣá agbẹjọ́rò fún Emefiele, Agbẹjọ́rọ̀ àgbà Joseph Daudu, SAN tako ìpè yìí pẹlú àwíjàre pé kí ìjọba kọ́kọ́ yẹ ara rẹ̀ wò lórí àìgbọràn rẹ̀ sí àṣẹ tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ pa pé kí wọ́n gba béélí Emefiele kí wọ́n tó gba ìpè wọn wọlé.
Onídájọ́ Nicholas Oweibo tó gbọ́ ẹjọ́ náà sún ìgbẹ́jọ́ sí Ọjọ́bọ ọjọ́ kẹtàdínlógùn oṣù kẹjọ ọdún 2023 láti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀bẹ̀ tuntun tí ìjọba àpapọ̀ gbé ka iwájú rẹ̀ náà.

Nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ lẹ́yìn ìjókòó ilé ẹjọ́ náà, adarí àgbà ní iléeṣẹ́ ètò ìdájọ́ ìjọba àpapọ̀ tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò fún ìjọba ṣàlàyé pé ogún ẹ̀sùn míràn ló tún ti jáde tí wọ́n ti fi kan Emefiele niíwájú ilé ẹjọ́ gíga àpapọ̀ tó wà ní ìlu Abuja tíí ṣe olú ìlú Nàìjíríà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here