Kìí ṣe agbe ni kí ẹni nílò ìrànwọ́ ó bèèrè—Yomi Fabiyi

Kìí ṣe agbe ni kí ẹni nílò ìrànwọ́ ó bèèrè—Yomi Fabiyi

Fẹ́mi Akinṣọlá

Àwọn àgbà ní tẹni tó dé larí,tẹni tó n bọ̀, a ò mọ̀ ọ́, àti pé èèyàn tí kò tíì kú , kò tíì lè sọ irúfẹ́ ikú tí yóó pa á.
Gbajúmọ̀ òṣèré fíìmù Yorùbá, Yomi Fabiyi náà ti jáde láti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn àgba òṣèré kan ṣe ń bọ sórí ayélujára láti pariwo fún ìrànwọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́yinjú àánú.

Yomi ń sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí èsì sí fídíò kan tí àgbà òṣèré bìnrin, Jaiye Kuti fi síta nínú èyí tó ti ń fẹnu sáátá bi àwọn òṣèré kan ti sọ ara wọn di alágbe.

Yomi Fabiyi bu ẹnu àtẹ́ lu ìwòye wí pé àwọn tó ń tọrọ fún ìrànlọ́wọ́ ń dójú ti àwọn òṣèré tókù ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dárúkọ tàbí na ìka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Jaiye Kuti, Yomi Fabiyi ní kò tọ́ kí ẹnikẹ́ni bú wọn pé wọ́n ń bọ sí gbangba láti bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ lásìkò ìṣòro wọn.

“Gbogbo àwọn iṣẹ́ tó kù lóríṣiríṣi ẹ̀ka ló wà lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn nítorí ìdí èyí, ìpèníjà ìlera wọn ń rí àmójútó. Bẹ́ẹ̀ sì ni àkànṣe ètò adójútòfò wà fún owó ìfẹ̀yìntì àti ìlera wọn.”

Yomi jẹ́ kó di mímọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà òṣèré yìí tí wọ́n ní ẹ̀bùn eré ṣíṣe ni wọ́n ti yànjẹ gidi gan lórí ìtàgé tí wọ́n sì ti lo àtàwọn àti òógùn wọn láàrin agbo tíátà àti níta tí kò sì sí ẹni tó bá wọn wá ojútùú síi pàápàá ní ti ọ̀rọ̀ jí jí iṣẹ́ oníṣẹ́ tàbí wíwo fíìmù wọn lọ́nà àìtọ́.

“Ìbànújẹ ló tún wá jẹ́ pé àwọn òṣèré ayé òde òní ti ń pa wọ́n tì, dípò kí wọ́n máa lo àwọn àgbàlagbà yìí fún fíìmù kí wọ́n lè máa rí owó, wọ́n á kun ojú àwọn ọ̀dọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n jọ arúgbó.”

Ṣáájú ni Jaiye Kuti ti sọ nínú fídíò tó fi sí ojú òpó sítágíràmù rẹ̀ pé ìwà tí àwọn tó ń bẹ̀bẹ fún ìrànwọ́ yìí ń hù ń tàbùkù bá ẹgbẹ́ àpapọ̀ àwọn òṣèré (TAMPAN) àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here