Baálẹ̀ méjì dèrò ẹ̀wọn, ‘ilẹ̀ òòṣà’ ni wọ́n jí tà

Baálẹ̀ méjì dèrò ẹ̀wọn, ‘ilẹ̀ òòṣà’ ni wọ́n jí tà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Baálẹ̀, ọkọ ìlú méjì kan, Alàgbà Ọlalekan Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdún mejidinlọgọta, tí í ṣe Baálẹ̀ abúlé Agejo, àti Ọgbẹni Oluwaṣẹgun Konigbagbe, ẹni àádọ́ta ọdún, tóun jẹ Baálẹ̀ Abúlé Ake ti méjèèjì wà nijọba ìbílẹ̀ Ọbafẹmi Owode, ní ìpínlẹ̀ Ogun, ti ń fẹnu fẹ́ra bíi abẹbẹ ní keremọnje báyìí. Ohun tó gbé wọn debẹ ni pé wọ́n wọnú ilẹ̀ ìjọba tó jẹ́ tí ileeṣẹ redio ìpínlẹ̀ Ògùn, Ogun State Broadcasting Corporation (OGBC), wọn bu apá kan ilẹ̀ ọ̀hún tà fáwọn oníbàárà kan, wọ́n sì tún bẹrẹ sí i kọle sáwọn apá mìíràn.

Àwọ́n mẹ́rin mí-ìn tí wọ́n jọ lọ́wọ́ nínú àṣà pálapàla ọ̀hún ni Wasiu Ogunṣina, ẹni ọdún mọ́kànléláàádọ́ta, Babatunde Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdun mọkanlelọgọta, Kabiru Ọlafẹnwa, ati Dare Awodele.

Àlàyé tí Agbèfọ́ba, rìpẹ́kítọ̀ Adekanmi Adeusi, ṣe niwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Abẹokuta lọjọ, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje yii, lasiko tawọn afurasi ọdaran naa n fara han fungba akọkọ ni pe atawọn to jẹ baalẹ laarin afurasi yii, atawọn ti ki i ṣe baalẹ, o ni iṣẹ ajagungbalẹ ni wọn n ṣe rẹbutu, iwa agba-lọwọ-merii, ati ilaalaṣi ọmọlakeji ẹni lori dukia rẹ lo kun ọwọ gbogbo wọn.

Ó ní ìwà irufin yìí náà ló mú káwọn agbófinró lọọ fi pampẹ gbé wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, nigba tawọn alaṣẹ ileeṣẹ redio OGBC kọwe ẹsun ṣọwọ si ọfiisi Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun nipa bi awọn atilaawi yii ṣe wọnu ilẹ onilẹ, ti wọn si n ta a, ti wọn n fowo ẹ ṣara rindin.

Ó lẹ́sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n ọ̀hún ta ko iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, ati pe ijọba ipinlẹ ọhun ko fẹẹ gbooorun ẹnikẹni to ba n huwa ajagungbalẹ rara, mimu lawọn n fọwọ ṣinkun ofin mu ẹnikẹni to ba lọ n ṣe bii akilapa lori dukia ẹni ẹlẹni.

Nígbà tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ àwọn afurasí náà bóyá wọn jẹbi tàbí wọn kò jẹbi, gbogbo wọn láwọn kò jẹbi rárá.

Èyí ló mú kí Onídàájọ́, Ọṣibajo paṣẹ pe ki wọn rọ gbogbo wọn da sẹwọn na. Ọgba ẹwọn to wa lagbegbe Ibara, ni ki wọn ko wọn lọ, ibẹ ni wọn yoo si wa fun saa ọgbọn ọjọ, lati faaye silẹ ki wọn gbe faili ẹjọ lọ sọfiisi ajọ to n gba awọn adajọ nimọran.

Adájọ́ náà ní òun kò tí ì lánfààní láti gba béèlì wọn.

Lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ tó kan sí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù Kẹjọ, ọdún yìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here