Tinubu mú àyípadà bá àfikún owó orí tí Buhari ṣe

Tinubu mú àyípadà bá àfikún owó orí tí Buhari ṣe

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti buwọ́lu àwọn òfin tuntun mẹ́rin kan léyìí tí àyípadà òfin kan tí Ààrẹ àná Muhammadu Buhari ṣe kó tó kúrò lórí ipò.

Ọ̀kan lára àwọn òfin náà ni ìdádúró ṣíṣe àfikún owó orí àwọn iléeṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ àti àwọn ọjà tí wọ́n ń pèsè lábẹ́lé pẹ̀lú ìdá márùn-ún.

Òfin mìíràn ni yíyí ọjọ́ tí ètò Finance Act yóò gbéra sọ di ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 dípò kọ bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù Karùn-ún tí ààrẹ àná fi sí tẹ́lẹ̀.

Olùbádámọ̀ràn Ààrẹ lórí àwọn àkànṣe iṣẹ́, ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n inú, Dele Alake ló fi ìkéde yìí síta lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹfà oṣù Keje ọdún 2023 ní gbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní Abuja.

Alake ní àwọn ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti lè jẹ́ kí àádọ́run ọjọ́ tó yẹ kí wọ́n fún àjọ tó ń rí sí owó orí nílò láti fi mọ̀ nípa àwọn ìgbésẹ̀ náà pé.

Bákan náà ni Tinubu tún buwọ́lu àtúnṣe owó orí, ọ̀rọ̀ àwọn àjọ ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè tọdún 2023 tó yẹ kọ bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹta sí ọjọ́ Kìíní oṣù Kẹjọ ọdún 2023 pẹ̀lú ìbámu ètò National Tax Policy.

Ó fi kun pé ààrẹ tún ṣe ìdádúró gbígba owó orí lórí àwọn ìgò, iké tí wọ́n fi ń kó ọjà sí.

Ààrẹ tún ṣe ìdádúró owó orí tuntun tí ìjọba àná gbé lórí àwọn ọkọ̀ kan tí wọ́n ń gbé wọ orílẹ̀ èdè yìí láti òkè òkun.

Agbẹnusọ ààrẹ náà fi kun pé àwọn àṣẹ tuntun tí ààrẹ buwọ́lu yìí wáyé láti mú àdínkù bá ìpalára tí àwọn owó orí yìí ń kó bá àwọn iléeṣẹ́ àtàwọn ìdílé káàkiri orílẹ̀ èdè yìí.

Bákan náà ló tún ṣàlàyé pé ààrẹ ní ìfarajìn láti wá ojútùú àti láti ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ sísan owó orí lọ́nà tó pọ̀ lórí ọjà ẹyọ̀kan tí yóò sì ri pé ó máa pèsè àwọn nǹkan tí yóò mú kí ọjà gbèrú síi.

Tinubu sọ àrídájú rẹ̀ pé ìjọba kò ní èròǹgbà láti mú àlékún bá owó orí ti àwọn ènìyàn ń san tẹ́lẹ̀ tàbí ṣe ìgbéjáde owó orí tuntun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here