Ìgbésẹ̀ àti yan àwọn Kọmíṣọ́nà l’Ọ́ṣun kò ní pẹ́ mọ́–Adélékè

Ìgbésẹ̀ àti yan àwọn Kọmíṣọ́nà l’Ọ́ṣun kò ní pẹ́ mọ́–Adélékè

Fẹ́mi Akínṣọlá

Láti ìparí oṣù Kẹfa ọdún 2023 ni àwọn ènìyàn kan ti ń kùn pé tí a bá kà á ní ení, èjì, ó ti tọ́ oṣù méje tí gómìnà Ademola Adeleke ti gba ọ̀pá àṣẹ láti máa tukọ̀ ìpínlẹ̀ Osun fún ọdún mẹ́rin.

Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kọkànlá ọdún 2022 ni wọ́n búra wọlé fún Adeleke gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun lẹ́yìn tó fi ẹ̀yìn gómìnà àná, Gboyega Oyetola lulẹ̀.

Ní ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Keje ọdún 2022 ni ètò ìdìbò sípò gómìnà Osun wáyé tí àjọ elétò ìdìbò Nàìjíríà sì kéde pé Ademola Ademola tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ló jáwé olúborí ìbò náà pẹ̀lú ìbò 403,371.

Gómìnà àná ní Osun, Gboyega Oyetola tó díje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC tó ní ìbò 375,027 ni òun kò gbà èsì ìbò tó gbé Adeleke wọlé.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Supreme Court Kéde pé Ademola Adeleke ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, bí gómìnà Adeleke ṣe ti wọ ọ́fíìsì ni wọ́n ti ń fẹ́ ọ̀kan-ò-jọ̀kan àyípadà ní ìpínlẹ̀ Osun pàápàá lórí yínyan àwọn Kọmíṣọ́nà tí yóò ba ṣe ìjọba.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ ń bèèrè pé kí ló dé tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn oṣù méje gẹ́gẹ́ bí gómìnà Osun, gómìnà Ademola Adeleke kò ì tíì yan Kọmíṣọ́nà kankan títí di àsìkò yìí.

Nígbà tí Agbẹnusọ Gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed yóó fèsì, ó ní Gómìnà Adeleke ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.
Rasheed ní gbogbo àwọn ìpèníjà tí ìjọba àwọn kojú nígbà tí àwọn gba ọ̀pá àṣẹ láti tukọ̀ ìpínlẹ̀ Osun wà lára àwọn nǹkan tó ṣokùnfà ìfàsẹ́yìn láti yan àwọn kọmíṣọ́nà.

Ó ṣàlàyé pé gbogbo bí àwọn ṣe ń ti ilé ẹjọ́ kan bọ́ sí òmíràn lórí ta ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò ṣe ìdádúró àwọn ìgbésẹ̀ kan tó yẹ kí ìjọba ti gbé.

Agbẹnusọ gómìnà náà wá sọ àrídájú rẹ̀ pé gómìnà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti yan àwọn kọmíṣọ́nà tí yóò ba ṣiṣẹ́ tó sì ti ń ṣe àkójọ àwọn orúkọ kan.

“Láìpẹ́, láì jìnà ni gómìnà máa fi orúkọ àwọn kọmíṣọ́nà ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin.”

“Iṣẹ́ ti fẹ́ parí lórí àwọn tí wọ́n fẹ́ yàn gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nà, gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ ni ìjọba sì ti ń gbé báyìí.”

Ó fi kun pé ètò ìdìbò gbogbogbo tó wáyé ní Nàìjíríà náà wà lára ohun tó ṣe ìdádúrọ yíyan àwọn kọmíṣọ́nà náà di ìwòyí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here