Mi ò gba ìgboríyìn tó ye̩ bó ti lè̩ jé̩ pé èmi ni olórin tó dára jù lágbàáyá – Burna Boy

Mi ò gba ìgboríyìn tó ye̩ bó ti lè̩ jé̩ pé èmi ni olórin tó dára jù lágbàáyá – Burna Boy

Mary Fágbohùn

Olorin Naijiria olugbafe eye Grammy, Damini Ogulu, ti a mo si Burna Boy, ti so pe oun ko gba igboriyin ti o to bo ti le je pe oun “lo dara ju lo ni agbaye.”

Nigba ti awon akosemose ni ile ise naa bii asagbelaruge eto Naijiria ati British, Adesegun Adeosun Jnr, ti a mo si Smade, ati atokun eto Adesope ti a mo si Shopsydoo yi i ka, leyin ere to se nibi ajodun Afronation ni Portugal, Burna Boy so pe oun ko da ara oun laamu nitori oun ko gba igboriyin ti o to nitori pe Jesu ko gba igboriyin titi di eyin igba ti o fi ku.

Olorin ‘African Giant’ ninu fonran kan to n lo kaakiri, so pe oun dupe nitori awon eniyan n jerisi pe oun ni olorin to dara ju lo lagbaye.

Ninu fonran, Smade ni a gbo to n so wi pe “Burna, o sa n bukun wa. Rara, o o ti gba igboriyin ti o to arakunrin. Iwo lo dara ju lo ni agbaye.”

Burna Boy fesi o ni: “Rara, Mi o gba a [gboriyin to ye]. Jesu pelu ko gba igboriyin di eyin igba ti o ku, nitori naa ta ni mi? [o rerin]”

Shopsydoo fikun un: “Kii se nipa ti orin takasufe Afrika mo, o je nipa gbigba gbogbo agbaye.”

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here