Ó súnmọ́ kí n gbá ojú Kwankwaso bí a bá pàdé nílé Ààrẹ ní Abuja- Ganduje

Ó súnmọ́ kí n gbá ojú Kwankwaso bí a bá pàdé nílé Ààrẹ ní Abuja- Ganduje

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní àwo pẹ̀lẹ́ kìí fọ́,ìgbá pẹ̀lẹ́ kìí fàya. Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ti sọ pé kání òun àti ẹni tó di ipò náà mú saájú òun , ìyẹn Abdullahi Ganduje bá pàdé ara wọn ní ilé-iṣẹ́ Ààrẹ Nàìjíríà, lọ́jọ́ Ẹtì tí àwọn méjèèjì lọ kó ẹjọ́ bá Ààrẹ ni, ó ṣeéṣe kí òun fọ́ ọ létí.

Ganduje sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó fi n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ipade rẹ pẹlu aarẹ Tinubu lọ́jọ́ Ẹtì.

Ganduje n bu ẹnu àtẹ́ lu Kwankwaso lori ohun to pe ni igbesẹ gomina to wa lode nipinlẹ naa lọwọ, Yusuf Abba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Kwankwaso, n gbe lati wo awọn ile kan nipinlẹ naa.

Kwankwaso ni olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP fún ìbò Aarẹ tó kọjá, ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ ló sì borí ìbò Gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kano.

Bákan náà ni Ganduje pẹ̀lú ti fi ìgbà kan ri jẹ́ igbákejì fún Kwankwaso nigba to di ipo gomina mu ni ipinlẹ Kano, ki tírélà tó gba Ààrin wọn kọjá.

“Mo mọ̀ pé ó wà ni agbègbè ile nla yii ṣugbọn a ko tii pade. Boya Ká ní a lọ pade ni , bóyá ìgbájú olóòyì ni ǹbá kó fún un.”

Ganduje ṣàlàyé pé, bóyá ló pé ọjọ́ mẹ́ta lẹyìn tí Abba Yusuf wọle gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ naa tó fi wo awọn ile mẹrin to jẹ ajumọni laarin ijọba at’awọn aladani kan ni Kano.

Ó ní òun ti fi ọ̀rọ̀ náà tó ọ̀gá agba iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí. Bákan náà ó ní òun ti ṣàlàyé gbogbo bí nnkan ṣe lọ lórí rẹ̀ fún Ààrẹ Bọla Tinubu.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here