Ọwọ́ tẹ afurasí olè tó n jí orúkọ àwọn òkú ní ibojì

Ọwọ́ tẹ afurasí olè tó n jí orúkọ àwọn òkú ní ibojì

Fẹ́mi Akínṣọlá

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano kéde pé ọwọ́ òun ti tẹ arákùnrin ẹni ọdún mọ́kàndínlógún kan tó kúndùn láti má a yọ àwọn irin pẹlẹbẹ tí wọ́n kọ orúkọ àti ọjọ́ ikú àwọn òkú sí ní ibojì.

Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kano, SP Abdullahi Kiyawa, sọ pé irin méjìdínlọ́gbọ̀n ni wọ́n rí gbà lọ́wọ́ afurasí náà lẹ́yìn tó kó wọn ní ilẹ̀ ìsìnkú Tudun Wada nílùú Kano.

Afurasí náà ni wọ́n ní ó jẹ́wọ́ fún àwọn ọlọ́pàá pé, aago mẹ́ta òru ni òun má ń lọ sí ilẹ̀ ìsìnkú láti jí àwọn irin náà.

Ó ní òun má ń ta àwọn irin náà fún àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń fi wọ́n rọ àwọn nǹkan míràn.

Ìròyìn sọ pé N300 ló má a ń ta kílógíràmù irin kan.

SP Kiyawa sọ pé àwọn yóó gbé e lọ sílé ẹjọ́, ni kété ti ìwádìí bá parí lórí ẹ̀sùn ti wọ́n fi kàn án.

Òṣìṣẹ́ kan ní ilẹ̀ ìsìnkú, Magaji Adamu, tó ti ń ṣiṣẹ́ láti ọdún náà fún ọdún marundinlọgbọn sọ pé irú nǹkan báyìí ko jẹ tuntun.

Ó ní ọwọ́ ti tẹ irú olè bẹ́ẹ̀ ní ìgbà méjì, ní ilẹ̀ ìsìnkú tí òun ti ń ṣiṣẹ́ lásìkò tí wọ́n wá yọ àwọn irin pẹlẹbẹ tí wọ́n kọ orúkọ àti ọjọ́ ikú àwọn òkú sí.

“Kódà, ilé ẹjọ́ rán olè tí a kọ́kọ́ mú lọ sí ẹ̀wọn fún ọdún méjì .”

Arákùnrin Adamu sọ pé ìwà àrífín àti ẹgbin ni irú nǹkan báyìí jẹ́ sí àwọn òkú, àti fún ilẹ̀ ìsìnkú tó yẹ kó jẹ́ ibi ìsinmi fún àwọn ara tó ti fi ayé yìí sílẹ̀ .

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here