Subomi Balogun ,Iṣẹ́ rere a máa fọhùn lẹ́yìn oníṣẹ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwáyé è kú kò sí, kóówá ń relé lẹyìn ìnájà ayé dandan ni. Ní ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlógún oṣù Karùn-ún ọdún 2023 ni ìròyìn gbòde pé olóyè Subomi Balogun tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ First City Monument Bank (FCMB) jáde láyé.
Ìròyìn sọ pé ní ìlú London, United Kingdom ni bàbá náà dákẹ́ sí lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́. Ó ṣeéṣe kí nífẹ̀ẹ́ àti mọ̀ irúfẹ́ èèkàn iràwọ̀ àwùjọ tí à n perí, gbàyí wò.
Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹta ọdún 1943 ni wọ́n bí olóògbé Subomi Balogun sáyé tó sì pé ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rùn-ún kó tó dágbẹre fáyé pó di kése.
Ọmọ ìdílé Ọba Tunwase ti Ijebu-Ode ni Subomi Balogun.
Òun ni Otunba Tunwase gbogbo Ijebu, tó sì tún jẹ́ Olori gbogbo ọmọọba Ijebu àti Asiwaju àwọn onígbàgbọ́ ní Ijebu.
Ìdílẹ̀ mùsùlùmí ni wọ́n bi sí kó tó yípadà sí onígbàgbọ́ nígbà tó wà ní ilé ẹkọ girama.
Ilé ẹ̀kọ́ Igbobi College ló ti kẹ́kọ̀ọ́ girama, kó tó tẹ̀síwájú lọ sí London School of Economics níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ òfin.
Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ kó tó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ kàwé, tó sì tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ nígbà tó padà sí Nàìjíríà lẹ́yìn ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Ní ọdún 1979 ni ó gba ìwé àṣẹ láti dá ilé ìfowópamọ́ First City Merchant Bank sílẹ̀ tí báǹkì náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1983.
Subomi Balogun dá ilé ìwòsàn fún àwọn ọmọdé kalẹ̀ ní Ijebu Ode èyí tó fún ile ìwòsàn ńlá UCH tí Ibadan.
Aṣọ funfun ni ó sábà máa ń wọ̀ ní gbogbo ìgbà. Olóògbé Subomi Balogun fi ọ̀pọ̀ ọmọ àti ọmọọmọ sáyé lọ .
Kín la á sọ nípa tèmi tì ẹ?