À ń ṣètò pẹ̀lú ìlẹ̀ Egypt láti kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní Sudan – ìjọba àpapọ̀

À ń ṣètò pẹ̀lú ìlẹ̀ Egypt láti kó àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò ní Sudan – ìjọba àpapọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀rọ̀ àwọn àgbà sọ pé kò sí kékeré ìdààmú àti pé ogun kìí bímọ ọ re.Ọmọ́ wọn kú sì tún sàn ju ọmọ wọ́n nù.
Kìí ṣe nnkan gidi kí ọmọ ẹni ràjò kó rá sájò Ìjọba Nàìjíríà ní àwọn ti ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè Sudan ni àwọn dá padà sílé.

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Geoffrey Onyeama tó sọ àrídájú yìí ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ láti rí i pé àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè náà padà sílé láyọ̀ àti àláfíà.

Onyeama ní ohun tó ń dá àwọn dúró láti kó àwọn ènìyàn náà ni pé kò sí ààyè láti lo ọkọ̀ òfurufú ní Sudan báyìí nítorí wàhálà tó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ó ní ọkọ̀ ni àwọn fi lè kó àwọn ènìyàn ọ̀hún tí àwọn sì nílò àṣẹ ìjọba Sudan láti kó wọn gba Egypt lábẹ́ ààbò tó péye.
Mínísítà náà ní tí ó bá máa fi tó ọjọ́ méjì sí mẹ́ta àwọn máa ti fẹnukò pẹ̀lú ìjọba Sudan àti ti Egypt tí àwọn yóò si ti mọ bí àwọn yóò ṣe kó àwọn ènìyàn náà kúrò.

Ó tún ṣàfọ̀mọ́ ẹ̀ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé ìjọba Nàìjíríà kò kóbi ara sí ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún ń kojú.

“Kò sí ẹni tó mọ̀ wí pé wàhálà tó ń wáyé ní Sudan máa fẹjú tó báyìí, ààbò ẹ̀mí àti dúkìá gbogbo ọmọ Nàìjíríà nílé lóko jẹ́ èyí tó jẹ ìjọba lógún.”

Ó fi kún-un pé ẹgbẹ̀rún márùn-ún àbọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti fi ìfẹ́ hàn sí pé àwọn ti ṣetán láti padà wá sílé tó sì ní púpọ̀ nínú wọn lọ́ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́.

Onyeama tún tẹ̀síwájú pé àwọn àjọ ìjọba tún ti ń gbìyànjú láti pèsè ohun ìdẹ̀kùn fún àwọn ènìyàn náà, ó ní láìpẹ̀ ọ̀rọ̀ nàà yóó lójútùú.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here