Ìpàdánù o̩mo̩ kò ye̩ èmi àti Chioma – Davido

Ìpàdánù o̩mo̩ kò ye̩ èmi àti Chioma – Davido

Mary Fágbohùn

Onirawo olorin takasufe Davido ti soro nipa ipapoda omokunrin re, Ifeanyi Adeleke.

O wi pe oun ati iyawo oun, Chioma, ko ye ki won padanu re.

Olorin naa, eni to sese gbe awo orin re tuntun eleekerin jade ‘Timeless’, soro ninu iforowero kan pelu CNN.

O wi pe isele aburu naa ti omo odun meta re ti re koja lo je ki agbejade awo orin oun fa seyin bi oun ati awon ololufe oun see n kedun oro naa.

“Ki omokunrin mi to re koja lo, a ti pari awo orin naa. Sugbon isele aburu naa lo kami lowo ko ati pe ohun lo mu ki n gbe ese seyin ,” ni Davido so.

Oga DMW naa sibesibe salaye pe ife alailegbe ati atileyin ti o ri gba lodo gbogbo eniyan lo mu ki ese oun le e duro lati wa se nnkan ti oun nife si lati se ju.

“Ohun kan ti mo so pe o ranmi lowo ni atileyin. Atileyin lati odo gbogbo eniyan ti mi o ti ba soro ni opolopo odun seyin. Ati pe, e mo pe ko si enikeni to fe iru nnkan be e,” ni o so, ni titokasi iku omokunrin re kekere naa.

“Gbogbo eniyan lo mo pe emi ati Chioma ko ye fun iru re. Ti enikeni ninu aye ba tile feran iru ‘nnkan to ye won’ be, kii se awa.

“Ni temi, atileyin ti mo ri gba lati odo awon eniyan ni nnkan to ranmi lowo lati le e dide leekan si.

“Mo ranti pe mi o tie le e si oju opo Instagram mi fun ose meta. Ni ojo kan mo kan so pe ‘E, e mu ero ibanisoro mi wa ki n wo’. Mo kan wo ni mo wa n ri opolopo ateranse lati odo oniruuru eniyan ninu aye, ti e ba le ro.

“Lati odo awon oloselu titi de awon elere idaraya si awon olorin miran, si awon aare. Iyen je nnkan to fun mi lokun ti o to lati dide leekan si, pada si yara igborinsile. Ati pe mo si pada si nnkan ti mo feran lati maa se.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here