Àwo̩n obìnrin tó ti mo̩ o̩kùnrin máa ń se ìpinnu tó dára– OAP Nedu

Àwo̩n obìnrin tó ti mo̩ o̩kùnrin máa ń se ìpinnu tó dára– OAP Nedu

Mary Fágbohùn

Olootu eto Chinedu Ani Emmanuel ti a mo si Nedu ti jiyan pe awon obinrin to ti mo okunrin maa n se ipinnu to dara ju eni ti won je lo.

O so pe opolopo awon obinrin ti ko ti mo okunrin ri ibaale won bi nnkan ti kii se iyi tabi nnkan to se iyebiye fun won julo nikan sugbon bii gbogbo nnkan fun won, o jiyan pe won ko ni nnkan miran ju iyen lo.

Ni ori eto kan o woye nnkan ti won yoo da bi o ba sele pe won so ibaale won nu.

“Bi mo ba fe se igbeyawo, Mi o le fe obinrin ti ko ti mo okunrin,” ni oun to si ni ori eto kan to sese se ‘Honest Bunch Podcast’.

“Pe o je eni ti ko ti mo okunrin ko tumo si pe iwo ni obinrin to dara ti okunrin kan le e fe.

“Fun emi o, kinni idi ti mo ro pe o ye ki o fe obinrin ti o ti mo okunrin, awon obinrin to ti mo okunrin, bi ero temi, maa n se ipinnu to dara nitori pe awon obinrin ti ko ti mo okunrin gbagbo pe ibaale won ni nnkan iyi ati iyebiye ti won ni,

“Won a so pe ibaale mi ni eni ti mo je gege bi obinrin. Gbogbo nnkan ni. Mo je omo ogbon odun mi o si ti mo okunrin.

“Eyi tumo si pe, gbogbo iyi gege bi obinrin ni ibale won, nitori naa ti won ba se igbeyawo ti oko won ba si ja ibale won, kinni yoo pada di ti won?

“Ni iru oro bayii, gbogbo nnkan ti okunrin ba so fun won ni akoko naa, won a faramo, sugbon obinrin to ti ni iriri, o ni erori lati mo pe nnkan to dara ni tabi nnkan ti ko dara.

“Sugbon iyen ko so pe nnkan buburu ni pe ki obinrin je eni ti ko ti mo okunrin, ero temi ni.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here