Ìdí tí mo fi sá kúrò nílé – Ijo̩ba Lande

Ìdí tí mo fi sá kúrò nílé – Ijo̩ba Lande

Mary Fágbohùn

Aderinposonu lori ayelujara, Ganiyu Kehinde ti a mo si Ijoba Lande, eni to pada wa sile leyin ojo merin ti awon ebi ti kede pe won o ri, ti soro lori idi to fi kuro nile.

Aderinposonu naa, ni ori abala isoro kan ni Instagram, so pe aheso oro lasan ni pe won ji oun gbe.

O gba pe oun kuro nile ni abe ikolu nipa ti emi.

O wi pe: “Mo wa labe ikolu nipa ti emi ni. Mo kuro nile funra mi nitori pe gbogbo awon asotele ti mo gbo nipa ara mi ti bere si ni wa si imuse.”

Gege bi o se so, awon wooli kan so fun un pe owo re yoo kan isale apo, yoo je gbese, yoo ta awon nnkan ini re ati pe yoo fi ese rin de gbogbo ibi to wa oko de.

O dupe lowo awon akegbe ati afenifere re fun igbiyanju won nigba ti o sonu, o wi pe: “Mo dupe lowo gbogbo eniyan. Won so pe gbogbo eniyan lo fere fi atejade an lede.

“Mo fe so fun gbogbo eniyan pe ooto ni irewesi okan, ati pe mo fe so fun gbogbo eniyan pe ko si eni to ji mi gbe. Mo moomo see ni sugbon mo dupe lowo Olorun mo ti pada wa.”

Ni ojo die seyin, iyawo aderinposonu naa lo si oju opo Instagram re, o si kede sita nipa bi won o se rii.

O wi pe oko oun sonu, wi pe o kuro nile ni ale ojo Aiku, ojo kerin-din-ni-ogbon osu keta leyin to sinu awe tan lai mu ero ibanisoro re lowo ati pe ko si pada wale lati igba naa.

Awon akegbe ati afenifere lo si ori ayelujara lati fi aworan Lande lede ti won si n beere boya enikeni mo ibi to wa.

Amo sa, o pada sile leyin ojo merin ni ogbonjo osu keta pelu awon ebi re leyin ti awon olode adugbo ri ni Igando ti won si pe ero ibanisoro iyawo re ki won le e fi to won leti. Won rii nibi ti ara re ko ti bale to si ri bi eni ti ko ni itoju.

Ninu fonran ipadabo wa re ni oju awe re, aderinposonu naa bu si ekun nigba to fi ese si inu ile re leyin ti awon ebi ati ore re sin in de ile.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here