N kò lè jẹ́ ọmọ Nàíjíríà mọ́ bí Tinubu ti di Ààrẹ – Igbákejì gómìnà àná l‘Eko

N kò lè jẹ́ ọmọ Nàíjíríà mọ́ bí Tinubu ti di Ààrẹ – Igbákejì gómìnà àná l‘Eko

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní èèyàn tí kò bá gbọ́ tẹnu ẹ̀gà ni yóó pè é lẹ́yẹ oní wótòwótò.
Igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Eko, Alhaja Sinatu Ojikutu ní òun ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yí jíjẹ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà.

Ojikutu nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú ní torí pé Tinubu ló jáwé olúborí ìdìbò Ààrẹ ni òun ṣe fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ ọ̀hún.

Ó ní gbogbo ètò ti ń lọ láti parí ìgbésẹ̀ náà kó tó di ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún tí wọ́n máa búra wọlé fún Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Nàìjíríà.

Ó ṣàlàyé pé kí èsì ìbò Ààrẹ tó jáde ni òun ti kéde pé tí Tinubu bá wọlé Ààrẹ, òun máa fi Nàìjíríà sílẹ̀.

“Àwọn agbẹjọ́rò ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yí jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà, mà á rí orílẹ̀ èdè kan tí inú mi yóò ti máa dùn gbé.”

“Mà á lọ máa gbé orílẹ̀ èdè tí ìwà ìbàjẹ́ wọn kò ti pọ̀ tó ti Nàìjíríà.”

Ojikutu tún tẹnu bọ̀rọ̀ pé òun ké gbàjarè síta nígbà tí òun gbọ́ pé Tinubu ń wádìí bóyá òun ṣì wà láyé.

Ó ní tí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí òun, ọwọ́ Tinubu ni kí àwọn ènìyàn ti bèèrè.

Ó fi kun pé gbogbo ìgbìyànjú láti parí aáwọ̀ tó wà láàárín òun àti Tinubu ló já sí pàbó.

Igbákejì gómìnà tẹ́lẹ̀ rí náà ní òun wà lára àwọn tó ní ìgbàgbọ́ pé ó yẹ kí Ààrẹ Nàìjíríà wá láti gúúsù ìlà oòrùn Nàìjíríà lásìkò yìí.

Ó ní ìdí nìyí tí òun ṣe kún Peter Obi lọ́wọ́
lásìkò ìpolongo ìbò.

Ojikutu tẹ̀síwájú pé ọ̀rọ̀ ti débi pé òun kì í fẹ́ sọ pé òun dipò òṣèlú mú rárá nígbà kan rí nítorí gbogbo ìpìlẹ̀ tí àwọn fi lélẹ̀ ló ti bàjẹ́ tán.

Ó fi kun-un pé gbogbo àwọn tó ti sin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tọkàntọkàn ni inú wọn kò dùn sí ipò tí orílẹ̀ èdè yìí wà báyìí.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here