Ẹ yanjú ẹjọ́ tó ṣú yọ lẹ́yìn ìdìbò kí wọ́n tó gbéjọba sílẹ̀– Agbakoba
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ṣé wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ bá pẹ́ nílẹ̀,níṣe ló má a ń gbọ́n síi.
̣Olórí ẹgbẹ́ àwọn amòfin nílẹ̀ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olisa Agbakoba, ti gba iléeṣẹ́ ètò ìdájọ ilẹ̀ Nàìjíríà nímọ̀ràn, pàápàá jù lọ, ẹ̀ka tí wọ́n ti ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ tó ṣúyọ lórí ìdìbò sípò Ààrẹ, láti jíròrò, kí wọ́n sì ṣe ìdájọ lórí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láàrin ọjọ́ méje tí wọ́n bá gbé e déwájú wọn.
L’Ọjọru ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lo sọrọ yii di mimọ lasiko to n sọrọ lori tẹlifiṣan Arise TV.
Bakan naa lo tun fi kun un pe oludije sipo yoowu ti yoo ba jẹ aarẹ gbọdọ ni ibo to to ida mẹẹẹdọgbọn, niluu Abuja, ki wọn too le kede ẹ pe oun lo wọle.
O ni, “Gẹgẹ bi emi ṣe mọ o, o gbọdọ tun ni bii ida mẹẹẹdọgbọn ibo lolu ilu orilẹ-ede wa, ṣugbọn iyẹn ki i ṣe fun emi lati sọ. Ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun to ba tibi eto idibo yọ le dahun ibeere yii lai si wahala, laarin wakati kan. Ki i ṣe ibeere to le rara”.
Ọrọ yii waye latari wahala to ṣu yọ lasiko tawọn ọmọ Naijiria fẹ tumọ abala kẹtalelaaadoje iwe ofin ilẹ Naijiria, to sọ pe ki wọn to le kede oludije sipo kan gẹgẹ bii aarẹ, o gbọdọ ni ida mẹrin ibo ti wọn di ni meji ninu ida mẹta awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede yii, titi to fi mọ ilu Abuja. Ṣugbọn ti agba lọọya yii sọ pe ofin yọ olu ilu orilẹ-ede yii sọtọ gedegbe, labẹ ọrọ naa.
Agbakoba tẹsiwaju pe pẹlu nnkan to n lọ yii, ọrọ oṣelu orilẹ-ede yii ti waa lagbara gan-an. O ni afi ti wọn ba le ṣe nnkan to tọ, iyẹn naa si ni pe ki wọn yanju awọn ẹjọ to jẹ jade latari eto idibo, o ni lẹyin eyi, gbogbo nnkan yoo pada bọ sipo.
“Lọjọ bii meloo sẹyin bayii ni Minisita fọrọ iroyin n naka aleebu si Peter Obi fun ẹsun pe o dalẹ ilu ẹ, ti oriṣiiriṣii ọrọ mi-in si n lọ bẹẹ bẹẹ. Ọpọlọpọ nnkan lo fẹẹ da orilẹ-ede yii ru, awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ (DSS) naa n pariwo pe awọn eeyan kan n ṣe kinni kan nibi kan. Nnkan to si n da gbogbo eleyii silẹ ko ju bi wọn o ṣe ti i yanju ẹjọ idibo yii lọ.
Ibeere to wa nilẹ bayii ki i ṣe pe ṣe nnkan to ṣee ṣe ni, ṣugbọn lati bi wọn pe ṣe wọn maa ṣe e. Nitori mo le sọ ọ pe ọrọ eto idajọ orilẹ-ede yii ti to bii ọgọrun-un ọdun, a o si ri ilọsiwaju kankan ninu Naijiria”.
Agbakoba ni awọn orilẹ-ede bii Ghana ati Kenya ti ni idagbasoke debii pe, laarin ọgbọnjọ tabi ko ma tilẹ to bẹẹ, ni wọn fi yanju ọrọ ẹjọ to ṣu yọ latara eto idibo.
“Bawo lo ṣe ṣee ṣe fawọn Ghana lati yanju tiwọn laarin ọgbọnjọ, ki lo de tawa naa o le ṣe e nibi? Ki lo de to jẹ ọọdunrun ati ọgọta ọjọ la fi maa maa ṣeto idibo? To ba jẹ emi ni adajọ ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun ibo yẹn ni, wakati meji pere ni mo maa fun awọn olupẹjọ lati mu ẹri wa lori boya o yẹ ki wọn wo ida mẹẹẹdọgbọn lori kikede aarẹ to ba wọle tabi ko yẹ. Ma a fun Ọgbẹni Tinubu naa lakooko lati fesi, nigba to ba si maa fi di aago mẹfa irọlẹ, mo maa ka idajọ seti gbogbo eeyan. Ki ni nnkan to waa le nibẹ, ọrọ imọ nipa ofin pọnnbele leyi, ki i ṣe nnkan to ruju rara”.
O ni ti eyi toun sọ yii ko ba waa le ṣiṣẹ, a jẹ pe ki wọn ṣayẹwo magomago to waye lasiko idibo ni yoo tun yanju ẹ, ati pe iyẹn kan le gba akoko pupọ ni. O ni ti wọn ba le yanju ẹ laarin ọjọ mẹrinla lorilẹ-ede Kenya, ki lo de to jẹ odidi ọdun kan ni yoo gba wa lati ṣe tiwa, abi a o kawe ju wọn lọ ni Kenya ni?
“Ohun to n ka mi lara bayii ni pe ọrọ oṣelu ti n gbona janjan, ọna abayọ to si wa bayii ni lati wo ba a ṣe le ri ọrọ ẹjọ yii yanju, ko too di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti wọn yoo gbe ijọba tuntun kalẹ”.
Agbakoba tún gbójú agan sáwọn tí wọ́n ní ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé lọ síwájú ilé-ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹ̀sùn ìdìbò kò lè yanjú kí ìjọba tuntun tóó wọlé. Ó láwọn tí kò fẹ́ kí Nàìjíríà gòkè nirú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀.