Pásítọ̀ hùwàa gbájú-ẹ̀ fáwọn tó wá ṣe ìsọjí fún n’Íbàdàn

Pásítọ̀ hùwàa gbájú-ẹ̀ fáwọn tó wá ṣe ìsọjí fún n’Íbàdàn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó sọ pé nígbà tí òpin ayé bá ń bọ, oríṣìíríṣìí ìṣẹlẹ̀ kayeefi ni yóó máa ṣẹlẹ̀. Irúfé ìṣẹ̀lẹ̀ irọlẹ ayé bẹ́ẹ̀ ló wáyé n’Ibadan lalẹ ọjọ́ Ìṣẹ́gun, tó kọjá nígbà tí odidi pasitọ kó owó, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àti nǹkan ẹ̀ṣọ́ ara àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ lọ lásìkò tí wọ́n dijú, tí wọ́n ń gbàdúrà lọwọ́.

Oun tí a gbọ pe Oluṣọ-Agutan naa, Pasitọ (Dokita) Owen Abraham, to jẹ ọmọ orile-ede Gambia, funra rẹ lo ṣagbekalẹ isọji ọlọjọ marun-un ọhun laduugbo Agbowo, n’Ibadan.

Ohun to si mu ki ero pọ daadaa laarin ọjọ maraarun ni bi Pasitọ Abraham ṣe kọ ọ sibi iwe ikede isọji naa pe oun yoo ṣeranlọwọ owo nla nla fawọn alaini, bẹẹ lawọn ọdọ yoo janfaani ẹbun ẹkọ-ọfẹ.

Lọjọ kọkanlelọgbọn (31), oṣu Kẹta, ọdun 2023, leto ọhun bẹrẹ, to si pari lọjọ Ìṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii kan naa.

Lọjọ ti isọji ọhun maa pari gan-an ni oluṣọ-agutan yii paṣẹ fawọn agutan rẹ pe ki gbogbo wọn ko ohun gbogbo to ba wa lọwọ wọn silẹ, ẹmi Ọlọrun sọ foun pe ko gbọdọ si foonu, owo, tabi ohunkohun to jẹ ti aye kankan lọwọ ẹnikẹni titi ti aṣekagba isọji naa yoo fi pari.

Gẹgẹ bii ilana awọn Onigbagbọ, nigba ti eto adura naa n lọ lọwọ, gbogbo wọn diju, ṣugbọn ki ni wọn gbadura tan si ni, oju ti awọn ọmọ ijọ yoo ya bayii, ati pasitọ, ati gbogbo nnkan ti wọn ko si dokita naa lọwọ ti poora.

Ọkan ninu awọn to padanu dukia wọn sọwọ wolii eke to pera ẹ lojiiṣẹ Ọlọrun yii, Abilekọ Grace Akintọla, fidi ẹ mulẹ pe awọn opó lo pọ ju nibi eto naa, nitori ileri iranlọwọ owo nla nla ti jagunlabi ṣe fawọn alaini.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Obinrin Ibo kan ta a jọ n gbe adugbo kan naa lo pe mi sibi isọji yẹn, o ni pasitọ yẹn ti ṣeleri pe oun maa fun awọn eeyan lowo nla nla, owo ti awọn oloṣelu gan-an ko le fun eeyan. Bẹẹ lo tun ni oun maa fun ẹnikan ninu awa ta a ba wa sibẹ ni odidi ile kan ti gbogbo nnkan ti pe sinu ẹ.

“Pasitọ yii ta ike omi kan fun wa ni ẹgbẹrun marun-un o din igba Naira (₦4,800), ọpọ eeyan lo sí ra omi yẹn.

” Pasitọ Abrahamu fi wá sílẹ̀ sínú aawẹ àti adua, nígbà tó di ọjọ́ aṣekagba ètò, ṣadeede la wá a tì, tí a kò rí i mọ́. Gbogbo ìgbìyànjú wa láti rí i bá sọrọ kò so èso rere, nítorí gbogbo bá a ṣe ń gbìyànjú láti pè é sórí fóònù rẹ̀ tó, aago rẹ̀ kò lọ rárá ”.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here