Ohun tá a mọ̀ nípa ìyá ọlọ́mọ kan tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé ìjọsìn Ondo rèé
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí òpin aye bá ti ń kànkùn gbọ̀n gbọ̀n gbọ̀n,onírúurú la ó má a gbọ́ sétí,èyí ló bí ìròyìn bí Pásítọ̀ ìjọ Oke-Irapada ní ìlú Alade, ìjọba ìbílẹ̀ Idanre, ìpínlẹ̀ Ondo, Kayode Salami bó ti ṣe kó sí gbagà ọlọ́pàá fẹ́sùn ìfipábánilòpọ̀ àti pípa arábìnrin kan.
Salami, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì ti wà ní àháma àwọn ọlọ́pàá báyìí látàrí bí wọ́n ṣe bá òkú arábìnrin kan, Adejoke Oloje ní ilé ìjọsìn rẹ̀.
Olóògbé Adejoke Oloje ni ìròyìn ní ó kó lọ sí ilé ìjọsìn náà láti máa gbé láti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kìíní ọdún yìí pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, ọmọ oṣù mọ́kànlá lọ́wọ́.
Adejoke àti àbúrò rẹ̀ kan, Aderonke ni wọ́n ní wọ́n jọ kọ́kọ́ lọ sí ilé ìjọsìn náà fún ìjọ́sìn kí Adejoke tó padà lọ sílé ìjọsìn láti máa lọ gbé.
Nígbà tí ìyá Adejoke tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Deborah ní ọmọ òun, Adejoke wá ṣe ìbẹ̀wò sí òun ní ìlú Idanre ni àmọ́ tó ṣàdédé kó ẹrù rẹ̀ jáde kúrò nílé ní ọ̀sán kan òru kan láìmọ̀ ibi tó lọ.
Ó ní nígbà tí òun ṣe ìwádìí ni òun ṣe àwárí rẹ̀ pé ilé ìjọsìn náà ní ọmọ òun wà àmọ́ nígbà tí òun débẹ̀ ọmọ òun kọ̀ láti tẹ̀lé òun padà sílé.
“Mo pè é ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti mọ ibi tó wà ṣùgbọ́n kò gbé ago rẹ̀ àmọ́ ènìyàn kan sọ fún mi ní ọjọ́ kan pé àwọn ri ní Alade pẹ̀lú Aderonke.”
“Nígbà tí mo pe Aderonke ló sọ fún mi pé ilé ìjọsìn ni Adejoke wà kìí ṣe ọ̀dọ̀ òun.”
“Mo lọ sí ilé ìjọsìn náà láti wa lọ àmọ́ nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó ṣàlàyé pé òun kò ní oúnjẹ nílé mo sì ṣèlèrí láti bá gbé oúnjẹ wá ní ọjọ́ kejì.”
“Mo bẹ́ẹ̀ pé kó kúrò ní ilé ìjọsìn náà ṣùgbọ́n ó kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní tẹ̀lé mi.”
Deborah ní nígbà tí òun máa dé ilé ìjọsìn náà ní ọjọ́ kejì ní nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ gẹ́gẹ́ bí òun ṣe ṣèlérí, òun kàn ń gbọ́ igbe ọmọọmọ òun ni tó ń sunkún rara.
Ó fi kun pé bí òun ṣe súnmọ́ ibẹ̀ láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní òun ri pé ilẹ̀kùn wà ní títì pa, tí òun sì fagbára já ìlẹ̀kùn náà àmọ́ ìyàlẹ́nu lọ jẹ́ fún òun láti rí ọmọ òun nílẹ̀ gbalaja.
“Mo bá ọmọ mi nílẹ̀ tí wọ́n bọ́ pátá nídìí rẹ̀ àmọ́ wọn ò bọ́ pátá náà tán, wọ́n bọ dé ibi ẹsẹ̀ rẹ̀ tí mo sì ké gbàjarè fún ìrànlọ́wọ́.”
Ó tẹ̀síwájú pé ìgbà tí àwọn dé ilé ìwòsàn, àwọn dókítà sọ fún òun pé ọmọ òun ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ tí òun sì gba àgọ́ ọlọ́pàá Idanre lọ láti lọ fẹjọ́ sùn.
“Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá Idanre nawọ́ gán pásítọ̀ náà, mo sì ṣe àkíyèsí pé ṣòkòtò pásítọ̀ náà ya lábẹ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gan.”
“Ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún ìdílé wa nítorí ó ní ọmọ oṣù mọ́kànlá lọ́wọ́ kí ikú òjijì yìí tó dé, ẹni tó bá ṣiṣẹ́ ibi yìí gbọ́dọ̀ fojú winá òfin.”
Nígbà tó ń sọ tẹnu rẹ̀, Pásítọ̀ Salami ní òun kò mọ nǹkankan nípa ikú Adejoke àti pé nípasẹ̀ Aderonke ni òun fi mọ̀ ọ́n.
Pásítọ̀ Salami lẹ́yìn ọjọ́ kejì tí wọ́n wá sílé ìjọsìn òun ni Adejoke padà wá bá òun pé òun fẹ́ máa gbé ní ilé ìjọsìn náà títí tí òun fi máa rí ibi tí òun máa gbé.
Ó ní òun gbà láti fun-un ní ọkàn nínú àwọn yàrá méjì tó wà nínú ilé ìjọsìn àmọ́ òun kò bèèrè nǹkan tó wáyé láàárín òun Aderonke tó fi fẹ́ máa wá gbé ilé ìjọsìn.
“Ilẹ̀kùn àbáwọlé kan ló wọ yàrá èmi àti yàrá tó ń lò nítorí náà mo máa ń ri tí mo bá ń jáde tàbí wọlé.”
Ó fi kun pé òun àti Adejoke jọ ṣe ìṣọ́ òru ní ó ku ọ̀la tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, tí òun àti ẹ̀ sì tún ríra kí òun tó máa lọ sí ibi iṣẹ́ wẹ́dà tí òun ń ṣe.
“Ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ló wá síbi iṣẹ́ mi láti wá gba iná sí fóònù rẹ̀, tó sì kúrò ní nǹkan bíi aago mẹ́rìn ìrọ̀lẹ́.”
Pásítọ̀ Salami ní tí òun bá ní nǹkan ṣe ni òun máa ń lo yàrá tó wà ní ilé ìjọsìn náà nítorí òun àti àwọn ẹbí òun ní ibi tí àwọn ń gbé nítorí náà òun kò mọ nǹkankan nípa ikú ọmọbìnrin náà.
“Mi ò fipá ba lòpọ̀, mi ò mọ nǹkankan nípa ikú rẹ̀.”
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá Ondo, Funmilayo Odunlami ní ẹjọ́ náà ti wà ní ìlú Akure fún ìwádìí tó péye.