Ikú dóró! ìgbákejì Gómìnà tó ṣẹṣẹ fipò sílẹ̀ jáde láyé

Ikú dóró! ìgbákejì Gómìnà tó ṣẹṣẹ fipò sílẹ̀ jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àìsàn la rí wò, àwọn àgbà sọ pé kò séèyàn tó rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́ tí wọ́n ló ṣe é, Ìgbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì, lábẹ́ ìṣèjọba Káyọ̀dé Fáyẹmí tó ṣẹṣẹ kógba wọlé, Ọ̀túnba Bisi Ẹgbẹyẹmi, ti kú lẹ́ni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin.

Oun tí a gbọ́ ni pé ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta tó ti tẹ bàbá tó ti fìgbà kan jẹ alága ìjọba ìbílẹ̀ Ado-Ekiti náà díẹ̀, tí wọ́n sì gbé e lọ sí ọsibítù aládàáni kan tí wọ́n ń pè ní Multisystem Hospital, nílùú Ado-Ekiti, tí í ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ ọhún fún ìtọ́jú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ irú àìsàn tó ń ṣe bàbá náà, ó padà kú sí ọsibítù ọ̀hún ní òru ọjọ́ Ẹtì mọ́jú àárọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù Kẹta yìí.

Láàrin ọdún 2018 sí 2022 ni ọkùnrin tó jẹ́ agbẹjọ́rò, tó sì tún jẹẹ́ olóṣèlú náà fi ṣe igbákejì gómínà lábẹ́ ọ̀gá rẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Káyọ̀dé Fáyẹmí.

Ọjọ́ kẹjọ, oṣù Karùn-ún, ọdún 1944 ni wọ́n bí ọkùnrin ọmọ bíbí ìlú Ado Èkìtì ọ̀hún.

Wọn kò tí ì kéde ikú ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n àwọn tó sún mọ bàbá náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọkùnrin náà ti rewalẹ àṣà.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here