Mo jẹ gbèsè tí apá mi kò ká torí mò ń wá iṣẹ́ ìyanu lọ́dọ̀ pásítọ̀”
Fẹ́mi Akínṣọlá
Bí ayé bá n lọ sópin, onírúrurú ni yóó máa wáyé.Èyí ló mú kí arábìnrin Evarline Okello sọ ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú ẹkún kíkorò lẹ́yìn tó yá owó láti fi san owó àgbà ìyanu fún pásítọ̀, tí ó ṣèlérí fún-un ,ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ kò rí bó ṣe fẹ́.
Arábìnrin Okello ń gbé ní agbègbè Kibera ní Nairobi tó jẹ́ olú ìlú orílẹ-èdè Kenya.
Okello pẹ̀lú omijé ní ojú ni òun kò leè san owó ilé tàbí fún àwọn ọmọ òun mẹ́rin ní oúnjẹ òòjọ́ wọn mọ́ nítorí gbèsè.
Lásìkò tí arábìnrin náà ń sọ ìrírí rẹ̀ fún akọ̀ròyìn, ó ní ìṣòro òun bẹ̀rẹ̀ lásìkò tí òun gbọ́ nípa pásítọ̀ kan tó gbóná jain, tí yóò fi òpin sí ìṣòro òun tí pásítọ̀ náà bá gbàdúrà fún òun.
‘’ Pásítọ̀ náà béèrè fún $115 (£96; 15,000 Kenyan shillings), kí òun fi lè gbàdúrà fún un’’
‘’Owó yìí ni wọn ń pè ní ọrẹ àtinúwá fún ìtẹ̀síwájú tí wọ́n ń pè ní ‘’seed offering’’ ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì .’’
Arábìnrin Okello náà yá owó náà lọ́wọ́ ọrẹ rẹ̀ láti ta pásítọ̀ ní ọrẹ nítorí ádùrá tí pásítọ̀ bá gbà yóò ṣí ọnà ìyanu sílẹ̀ fún arábìnrin náà.
Àmọ́ ó ṣeni ní àánú pé àgbà ìyanu náà kò wáyé, ohun gbogbo tilẹ̀ bàjẹ́ sí i ni fún obìnrin náà.
‘’Ohun gbogbo tilẹ̀ wá burú sí i, ó sì ti mú ayé sú mi’’