Dẹ́rẹ́bà tó wa bọ́ọ̀sì to kọlu rélùwéè l’Eko ti jọ̀wọ́ ara rẹ́ fún ọlọ́pàá

Dẹ́rẹ́bà tó wa bọ́ọ̀sì to kọlu rélùwéè l’Eko ti jọ̀wọ́ ara rẹ́ fún ọlọ́pàá

Fẹ́mi Akínṣọlá

Dẹrẹba tó wa ọkọ̀ bọọsi BRT tó forígbárí pẹ̀lú reluwé nílùú Èkó l’Ọjọbọ ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fá wọn agbófinró.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Sanwo-Olu ló sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwòsàn ńlá Fásitì ìpínlẹ̀ Èkó, LASUTH.

Awakọ̀ tó wa ọkọ̀ bọ́ọ̀sì BRT àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba náà ti kọ́kọ́ sá lọ ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀, kí ó tó di pé ó padà fara rẹ̀ hàn.
Gómìnà Sanwo-Olu ní awakọ̀ náà ti wà ní àkóso àwọn ọlọ́pàá báyìí.

Àwọn márùndínlọ́gbọ̀n ti gba ìtọ́jú kíákíá wọ́n sì ti ń gbé wọn lọ sí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba míràn káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó.

Gómìnà Sanwo-Olu tún fi kún un pé èrò márùndín láàdọ́rù-ún 85 ló wà nínú ọkọ̀ b bọ́ọ̀si náà, méjìlélógójìj nínú wọn ni ohun tó ṣe wọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ púpọ̀, mọ́kàndínlọ́gbọ̀n nínú wọn ló fara ṣèṣe púpọ̀, tí mẹ́jọ nínú wọn sì farapa fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.
Èèyàn mẹ́fà ló ti jáde láyé nínú àwọn èèyàn tó farakáásá ìjànbá náà. Méjì nínú wọn ni wọ́n gbé dé ilé ìwòsàn lókùú, ṣùgbọ́n mẹ́rin míràn jáde láyé lẹyìn tí wọ́n gbé wọn dé ilé ìwòsàn.

Ó fi kún un nínú àlàyé rẹ̀ pé àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń lọ pẹ̀lú àwọn òbí wọn tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba Èkó wà nínú ọkọ̀ bọọsi náà nígbà tí ìjànbá náà wáyé.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here