Tinubu padà sí Eko, Ó ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu

Tinubu padà sí Eko, Ó ní iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àpèjúwe bí ààrẹ tuntun tí ìlú dìbò yàn ṣe padà sí ìlú Èkó ko yàtọ̀ sí pé kí jagunjagun ìgbà a nì bá jàjàyè, tí wọ́n sì fẹ́ wọ̀lú padà lọ̀rọ̀ jọ lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ karùn-ún, oṣù Kẹta yìí, pẹlu bí òbítíbitì èrò ṣe tú jáde láti kí ààrẹ tuntun, Aṣíwájú Bọ́lá Ahmed Tinubu, káàbọ̀ padà sílùú Èkó, láti Àbújá.

Tìlù -tìfọn làwọn o lólùfẹ́ èèkàn olóṣèlú tó ti fìgbà kan jẹ Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó náà lọọ pàdé rẹ̀, bi wọ́n ṣe ń kọrin, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń jó, tí wọ́n sì ń kókìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi akọni ọkùnrin tó gbóúnjẹ fẹ́gbẹ́, tó sì gbàwo bọ̀.

Láti pápákọ̀ òfurufú Murtala Mohammed, MMIA, tó wà n’Ikẹja, làwọn èèkàn èèkàn lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, ti lọ̀ ọ́ pàdé Jagaban, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń pé ọ̀kan nínú àwọn orúkọ oyè rẹ̀.

Lára àwọn tí wọ́n lọ ọ kí i káàbọ̀ ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, Olórí àwọn òṣìṣẹ́ ọba, Ọgbẹni Tayọ Ayinde, Sẹnetọ Musiliu Ọbanikoro, àti àwọn òṣìṣẹ́ ọba mìíràn.

Láti Ikẹja ọ̀hún ni gbogbo wọn ti jùmọ̀ rìn pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ bọ̀gìnnì wọn gbogbo, tààrà ni wọ́n mórí lé ààfin Iga-Iduganran, ibẹ̀ ni Ọba Rilwanu Akiola, Ọba ìlú Èkó, ti kí Tinubu káàbọ̀, bẹ́ẹ̀ lẹsẹ̀ àwọn olóyè onífìlà funfun nílùú Èkó pé báákán síbẹ̀.

Ṣé tèwe-tàgbà ní-ín ṣapẹ́ wo líìlí, àti pé bí sìkìǹmidìn bá wọnú ọjà, tẹrú tọmọ ní-ín jó o.
Iṣẹ́ àṣelàágùn làwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò àtàwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ṣe kí wọ́n tóó jẹ́ kí Tinubu bọ́ọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, ìrìn tí kò yẹ kó gbà ju ìṣẹ́jú péréte náà sì gba àkókò gígùn kó tóó fáàyè wọlé, bó ti ń ṣíṣẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan ló ń juwọ́ sáwọn ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n wá ṣàyẹ́sí i rẹ̀ níbẹ̀.

Láàfin Ọba Akiolu, Tinubu ní ìrìn àjò tóun là kọjá láti àsìkò ìdìbò abẹ́lẹ́ tí wọ́n fi fa òun kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olùdíje, títí dìgbà tí ètò ìdìbò náà fi wáyé, tó sì parí lọ́sẹ̀ tó lọ yìí, kò yàtọ̀ sí ìdíje ife àgbáyé bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá tó máa ń wáyé, níbi tó jẹ́ ojú ogun àti eré ẹlẹ́mìí ẹṣin ni, síbẹ̀ ẹgbẹ́ kan ṣoṣo ni yóó gbé ife lọ sílé.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn fún àṣeyọrí rẹ̀, bákan náà ló dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọba Akiolu àtàwọn orí-adé gbogbo fún ádùrá àti ìfẹ́ wọn.

Lẹ́yìn èyí ló ṣàfihàn ìwé -ẹ̀rí i ‘mo yege’ tí àjọ elétò ìdìbò INEC fún un, ó sì ya fọ́tò pẹ̀lú Ọba àtàwọn ìjòyè láti ṣèrántí ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ ọ̀hún.

Ó wáá ṣèlérí pé gbogbo ẹ̀jẹ́ tóun jẹ́ lásìkò ìdìbò lòun yóó ṣiṣẹ́ lé lórí, òun ò sì ní í já àwọn tó rọ̀jò ìbò fóun àti gbogbo ọmọ Nàìjíríà kulẹ̀ tóun bá ti gbọ̀pá àṣẹ láìpẹ́.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here