Warri Pikin sò̩rò̩ lórí bí kò se retí ohun tó pò̩ láti ò̩dò̩ àwo̩n ènìyàn
Mary Fágbohùn
Ilumooka aderinposonu, Anita Asuoha, ti a mo si Real Warri Pikin, ti so pe iriri oun pelu ibanuje okan ti je ki oun ma reti ohun to po lati odo awon eniyan.
Ninu iforowero kan pelu Saturday Beats, o wi pe, “Sisegun ibanuje okan ko je ki n reti ohun po lati odo awon eniyan. Ko si eni to jemi ni nkankan mo de ro pe mi o ni eto si nkankan, ko dabi ti tele. Mo ma n rope bi mo ba ran enikan lowo ti mo si duro ti iru eni bee to ba digba temi o ye ki won le e duro ti emi naa. Sugbon, mo ti ko pe ti mo ba ran enikan lowo, Olorun nikan lo lee san funmi; kii se awon ti mo ran lowo. Oye aye ti wa ye mi si gidi, mo si ti ni imo ijinle si nipa ti imolara.”
Nigba to n soro lori adojuko re gege bi bi osere tiata , Asuoha wi pe, “Ara nnkan to je ipenija fun mi ni ibudo, nitori pe mo n gbe ni Abuja. O ma n gba awon agberejade (ti ko gbe ni Abuja) lati ro ti owo irinna ki won to fun mi ni ise. Ati pe, diduro ni ibi kan (lati ya fiimu) fun ose kan nigba ti owo ti won san ko wu eniyan lori ma n fa wahala. Ni bayii, mo le pa iye owo na pelu fonran iseju kan tabi ti mo ba gba eto ayeye. Sibesibe, gbogbo re da lori ife ti eniyan ni si ise owo.”
Nigba to n soro lori iriri re gege bi iya, Warri Pikin wi pe, “Ise titoju omo bi iya to ise. Mo ro pe ise to gbani lakoko julo ni aye ni, sugbon ohun lo tun ni ere ju. O je asopo ibanuje ati adun pelu rukerudo. Won o bi eniyan gegebi iya; won n ko ni. Enikan le je eniyan to dara sugbon ko je obi buburu. Ise iya gba opolo; ati pe o ko mi lati ni suuru ati ki n farabale gbo ju bi mo se n soro lo.”