Obiwon gbóríyìn fún kíkópa àwo̩n o̩do̩ nínú ètò ìdìbò – Obiora

Obiwon gbóríyìn fún kíkópa àwo̩n o̩do̩ nínú ètò ìdìbò – Obiora

Mary Fágbohùn

Olorin, Obiora Nwokolobia-Agu, ti a mo si Obiwon, ti se sadankata fun akitiyan awon odo ninu eto idibo gbogboogbo. O fikun n pe awon odo Naijiria ti bere sini mo pe agbara wa ninu ogulogo won.

Ninu iforowero kan pelu Saturday Beats, o wi pe, “Ife ti awon odo Naijiria ni fun eto idibo 2023 wu ni lori jojo. A o ti ni iru eyi ri. Lateyin wa, iwoye awon odo ni pe ‘eni ti won ba fe ni won a gbe sibe’. Sugbon bayii, a ti ni ofin idibo to dara ju ti tele lo. A ti wa n ri ni kedere pe ibo wa se pataki. Itaniji ti wa, awon odo ti wa ri pe agbara wa ninu ogunlogo won. O je ohun to wu ni lori. Sibesibe, a gbodo sora, ki won maa ba lo iwa ipa, eleyameya ati gbogbo awon nnkan to n dewa lona lateyin wa lodi si wa ni asiko awon odo yii.”

Olorin naa, eni to ya kuro ninu orin aye si orin ihinrere, fikun un pe ohun to se pataki si oun ni yiyi igbe aye pada. O wi pe, “Ise mi ni ifaraji si ihinirere. Sise iyebiye mi se pataki si mi, idi niyi ti mo fi fi orin mi ji sinu igbagbo mi lakoko. Ohun to se pataki funmi bayi ni pe ki orin mi fi owo kan aye ki o si yi igbe aye pada.”

Nigba ti won bii leere boya o ri atileyin gba latodo awon olorin ihinrere, o wi pe, “Mi o ni eto si nkankan. Mi o fe gbo kan le atileyin enikeni. Emi ni mo ni ipinnu; nitori naa bi mo ba ri atileyin, deede. Ati pe, bi mi o ri atileyin , ko si enikeni to wa nibe nigba ti a pe mi. Mo ro mo ipe mi, Olorun si n ranmi lowo.”

 

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here