Mo ko̩ owó tí ó tó mílíònù ló̩nà ogún náírà láti ò̩dò̩ olùdíje tí mi ò fé̩ – Ashmusy

Mo ko̩ owó tí ó tó mílíònù ló̩nà ogún náírà láti ò̩dò̩ olùdíje tí mi ò fé̩ – Ashmusy

 

Osere tiata Naijiria ati onifonran, Amarachi Amusi, ti a mo si Ashmusy, ti safihan pe oun ko owo ti o to milionu lona ogun naira lati se atejade ati dibo fun oludije fun ipo are kan.

Bo tile je pe, ko daruko oloselu naa tabi egbe oselu, osere naa ni oju opo Instagram so pe oun o setan lati ta okan oun fun esu nitori owo. Ashmusy tesiwaju pe fun ebi oun, oun gbodo ko iru nnkan bee lai tiju rara.

O ko o pe, “Ijewo, mo ri ifa owo ti o to milionu lona ogun naira lati se atejade fun oloselu kan. (Fun oludije ti a o fe). O wo ni loju, mi o le paro.

“Sugbon nigba ti mo ri pe mo fe ta okan mi fun esu ni, ti mo ri pe awon omo mi, omoomomi, ebi mi, ololufe mi, yoo maa jiya ni orile-ede yii. Nitori pe mo se ipinnu omugo lati se atejade/dibo fun eni ti ko ye. Mo so pe RARA!

“Nitori ni orile-ede yi, awon olowo gan an jiya. Bawo ni maa se sise takuntakun lati pa owo naira wole, ki iye naira naa bere si ni dinku bi omi inu ora lojoojumo. Ti e ba paro re si poun tabi dola, e sun ekun. E jowo o ti sun wa, e gbagbe. E jowo.”

Ashmusy saaju ti se esun kan to n lo kaakiri ni bi ose die seyin, pe oun ati onifonran miiran, Nons Miraj, n si ajosepo pelu oloselu alariyanjiyan, Dino Melaye.

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here