Ìbálòpò̩ wà kìí se nítorí o̩mo̩ bíbí – Iyabo Ojo

Ìbálòpò̩ wà kìí se nítorí o̩mo̩ bíbí – Iyabo Ojo

Osere tiata Iyabo Ojo ti tan imole si ibasepo to wa laarin oun ati ololufe re olokowo , Paulo Okoye ti a mo si Paulo nipa omo bibi.

Osere tiata naa safihan ipinnu won lati ma bimo.

Ninu eto ibanisoro kan lori Instagram pelu olootu, Daddy Freeze, tokotaya naa fagile omo bibi nigba ti olootu beere boya ki awon eniyan maa reti omo lati odo won.

Gege bi Paulo se so, eni odun  merin-din-ni-ogota pelu ololufe re eni odun marun-din-ni-aadota, eto kan soso to wa nile ni lati rin irinajo kaakiri agbaye ki won si jegbadun.

Iya omo meji naa wi pe awon omo won nise omo bibi kan leyin ti won ti fi ebi mo ebi ti won si ti segbeyawo nisuloka.

“Mo je eni odun merin-din-ni-ogota ati eni odun marun-din-ni-aadota, se e fe pa ni? Ibasepo wa fun igbadun aye wa ni. Lati rin irinajo kaakiri agbaye. Rara kii se fun wa. Awon omo wa loku ti yoo maa bimo,” ni ohun ti Paulo so.

Nigba to n daba ohun ti yoo se ti o ba fun  Iyabo loyun, olokowo naa wi pe: “Maa salo ni. To ba ni omo, maa salo, maa yi oruko mi pada. E o le momi mo.

Iyabo Ojo ni tire, se alaye pe: “Mi o kan ti e le ronu omo bibi lasiko yi. Bi mo ba ni omo bayii, iya a je Paulo nitori pe oun ni yoo toju omo naa.

O ti to odun meji-le-ni-ogun ti mo ti bimo gbeyin. Priscillia yoo pe omo odun meji-le-ni-ogun seyin ni osu to n bo. Mo ti ni akosile ibi ti mo fe lo, Paulo ni tire pelu.

“Nitori naa, aseese fe gbadun ni. Ise, irinajo ati igbadun. E duro fun awon omo wa lati mu ololufe won wa, leyin naa, a se igbeyawo fun won. Se e mo, won a se igbeyawo won a si bi omoomo fun wa.”

Ni osu kerinla 2022, ninu atejade ojo ibi re, Ojo safihan pe Oga agba fun Upfront and Personal Management, Paul Okoye, ti a mo si Paulo, ni ololufe re.

Saaju ikede re, osere tiata naa ti koko so lerefe wi pe oun n fe omokunrin Igbo kan ti o si seleri lati safihan re ti akoko ba to.

 

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here