Ẹ má fẹnu dá làásìgbò sílẹ̀, ẹ kí Tinubu kú oríire – APC

Ẹ má fẹnu dá làásìgbò sílẹ̀, ẹ kí Tinubu kú oríire – APC

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ohun tó dájú ni pé bí a bá ń tayò dandan ni kí ẹnìkan sáà jáwé olúborí. Olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ètò ìròyìn fún ìgbìmọ̀ ìpolongo ìbò ààrẹ fún Aṣíwájú Bọ́lá Tinubu, Délé Aláké, ti rọ àwọn olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti Labour, ìyẹn Alaaji Atiku Abubakar àti Peter Obi, láti tọ ọ̀nà àlàáfíà lórí àbájáde ètò ìbò yìí. Ó ní pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé èsì ìdìbò náà yóò ti tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ báyìí láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣojú ẹgbẹ́ kóówá wọn, kí wọ́n ṣe bí Jonathan, ìyẹn ààrẹ ilẹ̀ wa tẹ́lẹ̀ , ti ṣe lọ́dún 2015, kí wọ́n pe Aṣiwaju Tinubu, kí wọ́n kí i kú oríire pé òun ló wọlé ìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ Sátidé. Lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ló sọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé oníròyìn kan tó ṣe nílùú Abuja. Aláké ní, ‘‘Lọ́dún 2015, ààrẹ àná kò dúró kí Alága àjọ elétò ìdìbò kéde èsì ìdìbò náà tán tó fi pe Ààrẹ Muhammadu Buhari, tó sì kí i kú oríire, ní ìlànà ìfẹ àti àjọṣe ti ìjọba a àwa-ara-wa pè fún. Ó wá rọ Atiku Abubakar àti Peter Obi láti tẹlé ìgbésẹ yìí kan náà, dípò tí wọn yóò máa sọrọ tó lè dá ogun tàbí wàhálà sílẹ̀. Aláké ní ohun tó ti dáa jù lọ ni kí àwọn olùdíje méjèèjì fún ipò ààrẹ yìí pe Tinubu báyìí báyìí, kí wọ́n sì kí i kú oríire.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here